Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 4:8 - Yoruba Bible

8 Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Kaini si ba Abeli arakunrin rẹ̀ sọ̀rọ: o si ṣe, nigbati nwọn wà li oko, Kaini dide si Abeli arakunrin rẹ̀, o si lù u pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Kaini wí fún Abeli arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí a lọ sí oko.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti wà ní oko; Kaini da ojú ìjà kọ Abeli arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 4:8
23 Iomraidhean Croise  

Adamu tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọ́ ní Seti, ó ní: “Ọlọrun tún fún mi ní ọmọ mìíràn dípò Abeli tí Kaini pa.”


Ọmọkunrin meji ni mo bí. Ní ọjọ́ kan, àwọn mejeeji ń bá ara wọn jà ninu pápá, kò sì sí ẹnikẹ́ni nítòsí láti là wọ́n, ni ọ̀kan ninu wọn bá lu ekeji rẹ̀ pa.


Nígbà tí Abineri pada dé Heburoni, Joabu mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, níbi ẹnubodè, bí ẹni pé ó fẹ́ bá a sọ ọ̀rọ̀ àṣírí, Joabu bá fi nǹkan gún un ní ikùn. Bẹ́ẹ̀ ni Abineri ṣe kú, nítorí pé ó pa Asaheli arakunrin Joabu.


Nígbà tí ó jọba tán, tí ó sì ti fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, ó fi idà pa gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ati díẹ̀ ninu àwọn olóyè ní Israẹli.


Sanbalati ati Geṣemu ranṣẹ sí mi, wọ́n ní “Wá, jẹ́ kí á pàdé ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣugbọn wọ́n ti pète láti ṣe mí ní ibi.


Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi; o óo wà láìléwu, o kò sì ní bẹ̀rù.


Ọlọrun, ò bá jẹ́ pa àwọn eniyan burúkú, kí àwọn apànìyàn sì kúrò lọ́dọ̀ mi.


Ọ̀rọ̀ ìkà ati ẹ̀tàn ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. Ó ti dáwọ́ ire ṣíṣe dúró; kò sì hu ìwà ọlọ́gbọ́n mọ́.


Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn ju oyin lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìjà ni ó wà lọ́kàn rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ tutù ju omi àmù lọ, ṣugbọn idà aṣekúpani ni.


àfi ìbúra èké ati irọ́ pípa; ìpànìyàn, olè jíjà ati àgbèrè ni ó pọ̀ láàrin wọn. Wọ́n ń yẹ àdéhùn, wọ́n ń paniyan léraléra.


Nítorí ọmọkunrin ń tàbùkù baba rẹ̀, ọmọbinrin sì ń dìde sí ìyá rẹ̀, iyawo ń gbógun ti ìyá ọkọ rẹ̀; àwọn ará ilé ẹni sì ni ọ̀tá ẹni.


“Bí ẹnìkan bá kórìíra arakunrin rẹ̀, tí ó sì fi ohun ìjà gún un, tabi tí ó ju nǹkan lù ú láti ibi tí ó sápamọ́ sí, tí ẹni náà bá kú,


Ẹ óo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi kí ẹ lè fi orí gba ẹ̀bi ikú gbogbo eniyan rere tí ẹ ti ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀; ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí Abeli, ẹni rere títí fi dé orí Sakaraya, ọmọ Berekaya, tí ẹ pa láàrin àgọ́ mímọ́ ati pẹpẹ ìrúbọ.


ohun tí ó ṣẹ̀ lórí Abeli títí dé orí Sakaraya tí a pa láàrin ibi pẹpẹ ìrúbọ ati Ilé Ìrúbọ. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ìran yìí ni yóo dáhùn fún ẹ̀jẹ̀ gbogbo wọn.


Jesu sọ fún un pé, “Judasi! O sì fi ẹnu ko Ọmọ-Eniyan ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ láti fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́?”


Nípa igbagbọ ni Abeli fi rú ẹbọ tí ó dára ju ti Kaini lọ sí Ọlọrun. Igbagbọ rẹ̀ ni ẹ̀rí pé a dá a láre, nígbà tí Ọlọrun gba ọrẹ rẹ̀. Nípa igbagbọ ni ó fi jẹ́ pé bí ó tilẹ̀ ti kú, sibẹ ó ń sọ̀rọ̀.


ati ọ̀dọ̀ Jesu, alárinà majẹmu titun, ati sí ibi ẹ̀jẹ̀ tí a fi wọ́n ohun èèlò ìrúbọ tí ó ní ìlérí tí ó dára ju ti Abeli lọ.


Ó ṣe fún wọn! Wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Kaini. Wọ́n tẹra mọ́ ọ̀nà ẹ̀tàn Balaamu nítorí ohun tí wọn yóo rí gbà. Wọ́n dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ bíi Kora, wọ́n sì parun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan