Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 39:8 - Yoruba Bible

8 Ṣugbọn Josẹfu kọ̀, ó wí fún un pé, “Wò ó, níwọ̀n ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ ọ̀gá mi, kò bìkítà fún ohunkohun ninu ilé yìí, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ṣugbọn on kọ̀, o si wi fun aya oluwa rẹ̀ pe, kiyesi i, oluwa mi kò mọ̀ ohun ti o wà lọdọ mi ni ile, o si ti fi ohun gbogbo ti o ní lé mi lọwọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 39:8
15 Iomraidhean Croise  

Ẹnu alágbèrè obinrin dàbí kòtò ńlá, ẹni tí OLUWA bá ń bínú sí níí já sinu rẹ̀.


kí wọ́n baà lè pa ọ́ mọ́, kúrò lọ́dọ̀ alágbèrè obinrin, ati kúrò lọ́wọ́ onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀.


Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, o ò gbọdọ̀ gbà.


Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà, ọ̀rẹ́ àfẹnujẹ́ ni wọ́n, ṣugbọn ọ̀rẹ́ mìíràn wà tí ó fi ara mọ́ni ju ọmọ ìyá ẹni lọ.


Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó lọ bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀ rí, kò sí ẹni tí yóo ṣe bẹ́ẹ̀ tí yóo lọ láìjìyà.


Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ, ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára,


Nítorí náà, ó rí ojurere Pọtifari. Pọtifari mú un sọ́dọ̀ pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún òun, ó fi ṣe alabojuto gbogbo ilé rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ rẹ̀.


Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kì í fi nǹkan lé Josẹfu lọ́wọ́ kí ó tún bìkítà fún un mọ́, nítorí pé OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ohunkohun tí ó bá ṣe, OLUWA ń jẹ́ kí ó yọrí sí rere.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan