Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 39:7 - Yoruba Bible

7 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Josẹfu wu aya ọ̀gá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ọ́ pé kí ó wá bá òun lòpọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni aya oluwa rẹ̀ gbé oju lé Josefu; o si wipe, Bá mi ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 39:7
19 Iomraidhean Croise  

Bí ó ti ń gbé e fún un, ni Amnoni gbá a mú, ó wí fún un pé, “Wá, mo fẹ́ bá ọ lòpọ̀.”


Ojú wọn kún fún àgbèrè, kì í sinmi fún ẹ̀ṣẹ̀. Wọn a máa tan àwọn tí kò lágbára. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n ṣá rí owó lọ́nàkọnà. Ọmọ ègún ni wọ́n.


Àgbèrè tìrẹ yàtọ̀ sí ti àwọn aṣẹ́wó yòókù, kò sí ẹni tí ń wá ọ láti bá ọ ṣe àgbèrè; ìwọ ni ò ń fún ọkunrin ní ẹ̀bùn dípò kí wọ́n fún ọ! Èyí ni àgbèrè tìrẹ fi yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlòmíràn.


Nítorí gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìwòkúwò ojú ati afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe láti inú ayé.


Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obinrin pẹlu èrò láti bá a lòpọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀.


Ìwọ iyawo onípanṣágà tí ò ń kó àwọn ọkunrin ọlọkunrin wọlé dípò ọkọ rẹ.


“Mo ti bá ojú mi dá majẹmu; n óo ṣe wá máa wo wundia?


O mọ ìtẹ́ gíga ní òpin gbogbo òpópó. O sì ń ba ẹwà rẹ jẹ́ níbẹ̀, ò ń ta ara rẹ fún gbogbo ọkunrin tí wọn ń kọjá, o sì sọ àgbèrè rẹ di pupọ.


Nítorí náà ni òjò kò ṣe rọ̀, tí òjò àkọ́rọ̀ kò rọ̀ ní àkókò tí ó yẹ. Sibẹsibẹ, ẹ̀ ń gbéjú gbéré bí aṣẹ́wó, ojú kò sì tì yín.


Yóo bá dì mọ́ ọmọkunrin tí kò gbọ́n náà, yóo fi ẹnu kò ó lẹ́nu, yóo wí pẹlu ainitiju pé,


kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn, kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́.


A óo gbà ọ́ lọ́wọ́ obinrin oníṣekúṣe, àní lọ́wọ́ obinrin onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀.


Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán, sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ.


nígbà náà ni àwọn ẹ̀dá ọ̀run lọkunrin ṣe akiyesi pé àwọn ọmọbinrin tí eniyan ń bí lẹ́wà gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ èyí tí ó wù wọ́n lára wọn.


Ìwọ ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, o ò gbọdọ̀ gbà.


Owó tí aṣẹ́wó yóo gbà kò ju owó burẹdi lọ, ṣugbọn gbogbo ẹ̀mí rẹ ni alágbèrè yóo fi ọgbọ́n gbà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan