Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 39:5 - Yoruba Bible

5 Nígbà tí Pọtifari ti fi Josẹfu ṣe alabojuto ilé rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí bukun ìdílé Pọtifari, ará Ijipti náà, ati ohun gbogbo tí ó ní nítorí ti Josẹfu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potiferi ní, nílé àti lóko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 39:5
9 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Labani dá a lóhùn pé, “Gbà mí láàyè kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí, mo ti ṣe àyẹ̀wò, mo sì ti rí i pé nítorí tìrẹ ni OLUWA ṣe bukun mi,


‘Má bẹ̀rù, Paulu. Dandan ni kí o dé iwájú Kesari. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé Ọlọrun ti fi ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹni tí ó wọkọ̀ pẹlu rẹ jíǹkí rẹ.’


Orúkọ ọba óo wà títí lae, òkìkí rẹ̀ óo sì máa kàn níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn; àwọn eniyan óo máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún ara wọn, gbogbo orílẹ̀-èdè óo sì máa pè é ní olóríire.


N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, n óo bukun ọ, n óo sì sọ orúkọ rẹ di ńlá, tóbẹ́ẹ̀ tí o óo jẹ́ ibukun fún àwọn eniyan.


Ẹ jẹ́ kí á fi ìyìn fún Ọlọrun Baba Oluwa wa Jesu Kristi, tí ó ti fi ọpọlọpọ ibukun ti ẹ̀mí fún wa lọ́run nípasẹ̀ Kristi.


Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae; o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀.


Ọlọrun ranti Abrahamu, nígbà tí ó pa àwọn ìlú tí ó wà ní àfonífojì náà, níbi tí Lọti ń gbé run, ó yọ Lọti jáde kúrò ninu ìparun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan