Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 39:4 - Yoruba Bible

4 Nítorí náà, ó rí ojurere Pọtifari. Pọtifari mú un sọ́dọ̀ pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún òun, ó fi ṣe alabojuto gbogbo ilé rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Josefu si ri ojurere li oju rẹ̀, on si nsìn i: o si fi i jẹ́ olori ile rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní on li o fi lé e lọwọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Josẹfu sì rí ojúrere Potiferi, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potiferi fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 39:4
23 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Abramu dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun, kí ni o óo fún mi, n kò tíì bímọ títí di ìsinsìnyìí! Ṣé Elieseri ará Damasku yìí ni yóo jẹ́ àrólé mi ni?


Ó wí pé, “Ẹ̀yin oluwa mi, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má kọjá lọ bẹ́ẹ̀ láìdúró díẹ̀ lọ́dọ̀ èmi iranṣẹ yín!


Èmi iranṣẹ yín ti rí ojurere lọ́dọ̀ yín, ẹ sì ti ṣe mí lóore ńlá nípa gbígba ẹ̀mí mi là, ṣugbọn n kò ní le sálọ sí orí òkè, kí ijamba má baà ká mi mọ́ ojú ọ̀nà, kí n sì kú.


Abrahamu sọ fún iranṣẹ rẹ̀ tí ó dàgbà jù ninu ilé rẹ̀, ẹni tí í ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó ní, pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abẹ́ itan mi,


Ẹ ní mo ní àwọn mààlúù, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, agbo ẹran, àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin. Ẹ ní mo ní kí n kọ́ ranṣẹ láti sọ fún un ni, kí n lè rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ̀.”


Ṣugbọn Jakọbu dáhùn pé, “Rárá o, jọ̀wọ́, bí mo bá bá ojurere rẹ pàdé nítòótọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá lọ́wọ́ mi, nítorí pé rírí tí mo rí ojú rẹ tí inú rẹ sì yọ́ sí mi tó báyìí, ó dàbí ìgbà tí mo rí ojú Ọlọrun.


Ó bá bèèrè, ó ní, “Kí ni o ti fẹ́ ṣe gbogbo àwọn agbo ẹran tí mo pàdé lọ́nà?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Mo ní kí n fi wọ́n wá ojurere Esau, oluwa mi ni.”


Ṣugbọn Josẹfu kọ̀, ó wí fún un pé, “Wò ó, níwọ̀n ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ ọ̀gá mi, kò bìkítà fún ohunkohun ninu ilé yìí, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ mi.


Simiri, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun rẹ̀, alabojuto ìdajì àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣọ̀tẹ̀ sí i. Ní ọjọ́ kan, níbi tí ó ti ń mu ọtí àmupara ní ilé Arisa, alabojuto ààfin, ní Tirisa,


Ẹsita wú Hegai lórí, inú rẹ̀ dùn sí i pupọ. Ó fún un ní nǹkan ìpara ati oúnjẹ kíákíá. Ó tún fún un ní àwọn ọmọbinrin meje ninu àwọn iranṣẹbinrin tí wọ́n wà ní ààfin. Ó fún Ẹsita ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ní ibi tí ó dára jùlọ ní ibi tí àwọn ayaba ń gbé.


Iranṣẹ tí ó bá hùwà ọlọ́gbọ́n a máa rí ojurere ọba, ṣugbọn inú a máa bí ọba sí iranṣẹ tí ó bá hùwà ìtìjú.


Bí ọ̀nà eniyan bá tẹ́ OLUWA lọ́rùn, a máa mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá bá a gbé pẹlu alaafia.


Ẹrú tí ó bá mọ ìwà hù, yóo di ọ̀gá lórí ọmọ tí ń hùwà ìbàjẹ́, yóo sì jókòó pín ninu ogún bí ẹni pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ni.


Ṣe akiyesi ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọba ni yóo máa bá ṣiṣẹ́, kì í ṣe àwọn eniyan lásán.


Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ, ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀.


Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan.


Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀.


Iranṣẹ rẹ̀ náà bá dá a lóhùn, ó ní, “Obinrin ará Moabu, tí ó bá Naomi pada láti ilẹ̀ Moabu ni.


Saulu ranṣẹ sí Jese, ó ní, “Jẹ́ kí Dafidi máa bá mi ṣiṣẹ́ nítorí ó ti bá ojurere mi pàdé.”


Samuẹli ń dàgbà sí i, ó sì ń bá ojurere OLUWA ati ti eniyan pàdé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan