Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 39:3 - Yoruba Bible

3 Ọ̀gá rẹ̀ ṣàkíyèsí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati pé OLUWA ń bukun ohun gbogbo tí ó bá dáwọ́lé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Oluwa rẹ̀ si ri pe OLUWA pẹlu rẹ̀, ati pe, OLUWA mu ohun gbogbo ti o ṣe dara li ọwọ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 39:3
28 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun wà pẹlu ọmọ náà, ó dàgbà, ó ń gbé ninu aginjù, ó sì mọ ọfà ta tóbẹ́ẹ̀ tí ó di atamátàsé.


Ní àkókò náà, Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sọ fún Abrahamu pé, “Ọlọrun wà pẹlu rẹ ninu ohun gbogbo tí ò ń ṣe.


Nítorí náà, fi Ọlọrun búra fún mi níhìn-ín yìí, pé o kò ní hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi, tabi sí àwọn ọmọ mi, tabi sí ìran mi, ṣugbọn bí mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ náà yóo jẹ́ olóòótọ́ sí mi ati sí ilẹ̀ tí o ti ń ṣe àtìpó.”


OLUWA sì fara hàn án ní òru ọjọ́ tí ó rin ìrìn àjò náà, ó ní, “Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ, má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo bukun ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ nítorí ti Abrahamu iranṣẹ mi.”


Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé OLUWA wà pẹlu rẹ, ni a bá rò pé, ó yẹ kí àdéhùn wà láàrin wa, kí á sì bá ọ dá majẹmu,


Ṣugbọn Labani dá a lóhùn pé, “Gbà mí láàyè kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí, mo ti ṣe àyẹ̀wò, mo sì ti rí i pé nítorí tìrẹ ni OLUWA ṣe bukun mi,


Ẹran ọ̀sìn díẹ̀ ni o ní kí n tó dé ọ̀dọ̀ rẹ, díẹ̀ náà ti di pupọ nisinsinyii OLUWA ti bukun ọ ní gbogbo ọ̀nà nítorí tèmi. Nígbà wo ni èmi gan-an yóo tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkójọ àwọn ohun tí mo lè pè ní tèmi?”


OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ninu ilé ọ̀gá rẹ̀, ará Ijipti, níbi tí ó ń gbé. Àwọn ohun tí ó ń ṣe sì ń yọrí sí rere.


Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ hàn sí i, ó jẹ́ kí ó bá ojurere alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pàdé.


Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kì í fi nǹkan lé Josẹfu lọ́wọ́ kí ó tún bìkítà fún un mọ́, nítorí pé OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ohunkohun tí ó bá ṣe, OLUWA ń jẹ́ kí ó yọrí sí rere.


OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó ń ṣe. Ó gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ ọba Asiria, ó di òmìnira, ó kọ̀ kò sìn ín mọ́.


Bí o bá pa gbogbo òfin tí Ọlọrun fún Israẹli láti ọwọ́ Mose mọ́, o óo ṣe rere. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́.


Finehasi, ọmọ Eleasari ni olórí wọn tẹ́lẹ̀ rí, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.


Solomoni, ọmọ Dafidi, fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, OLUWA Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá.


Ó sin Ọlọrun nígbà ayé Sakaraya, nítorí pé Sakaraya ń kọ́ ọ ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Ní gbogbo àkókò tí ó fi ń sin Ọlọrun, Ọlọrun bukun un.


Mo fún wọn lésì pé, “Ọlọrun ọ̀run yóo mú wa ṣe àṣeyọrí, àwa iranṣẹ rẹ̀ yóo múra, a óo sì mọ odi náà, ṣugbọn ní tiyín, ẹ kò ní ìpín, tabi ẹ̀tọ́, tabi ìrántí ní Jerusalẹmu.”


Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń so ní àkókò tí ó yẹ, tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere.


Nígbà tó bá yá, eniyan mẹ́wàá láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè yóo rọ̀ mọ́ aṣọ Juu kanṣoṣo, wọn yóo sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí á máa bá ọ lọ, nítorí a gbọ́ pé Ọlọrun wà pẹlu yín.’ ”


Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo.


Ní ọjọọjọ́ ìsinmi, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa mú ọrẹ ninu ohun ìní rẹ̀, kí ó máa fi í sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun bá ti bukun un. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé ni ẹ óo ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gba ọrẹ jọ.


“Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà.


Ranti pé mo ti pàṣẹ fún ọ pé kí o múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn rẹ, nítorí pé èmi, OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ níbikíbi tí o bá ń lọ.”


N óo fi àwọn kan láti inú ilé ìpàdé Satani lé ọ lọ́wọ́, àwọn òpùrọ́ tí wọn ń pe ara wọn ní Juu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe Juu. N óo ṣe é tí wọn yóo fi wá sọ́dọ̀ rẹ, wọn yóo foríbalẹ̀ fún ọ, wọn yóo sì mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.


Ó ń ṣe àṣeyọrí nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀.


Saulu rí i dájúdájú pé OLUWA wà pẹlu Dafidi ati pé Mikali ọmọ òun fẹ́ràn Dafidi.


Samuẹli sì ń dàgbà, OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ó sì ń mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ṣẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan