Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 32:7 - Yoruba Bible

7 Ẹ̀rù ba Jakọbu gidigidi, ó sì dààmú, ó bá dá àwọn eniyan tí wọn wà pẹlu rẹ̀ ati agbo mààlúù, ati agbo aguntan ati àwọn ràkúnmí rẹ̀ sí ọ̀nà meji meji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Nigbana li ẹ̀ru bà Jakobu gidigidi, ãjo si mú u, o si pín awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, ati awọn ọwọ́-ẹran, awọn ọwọ́-malu, ati awọn ibakasiẹ, si ipa meji;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jakọbu fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ìbákasẹ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 32:7
22 Iomraidhean Croise  

Mo bẹ̀ ọ́, gbà mí lọ́wọ́ Esau arakunrin mi, nítorí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, kí ó má baà wá pa gbogbo wa, àtàwọn ìyá, àtàwọn ọmọ wọn.


Jakọbu rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú lọ sọ́dọ̀ Esau, ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Seiri, ní agbègbè Edomu.


Ó rò ninu ara rẹ̀ pé bí Esau bá dé ọ̀dọ̀ ìpín tí ó wà níwájú, tí ó bá sì pa wọ́n run, ìpín kan tí ó kù yóo sá àsálà.


Bí Jakọbu ti gbé ojú sókè, ó rí Esau tí ń bọ̀ pẹlu irinwo (400) ọkunrin. Ó bá pín àwọn ọmọ rẹ̀ fún Lea ati Rakẹli, ati àwọn iranṣẹbinrin mejeeji.


Lẹ́yìn náà ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtẹli, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún Ọlọrun, ẹni tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, tí ó sì wà pẹlu mi ní gbogbo ibi tí mo ti lọ.”


Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn, ó sì yọ wọ́n kúrò ninu ìṣẹ́ wọn.


Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan, tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà.


Mo wo ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi yíká, mo rí i pé kò sí ẹni tí ó náání mi; kò sí ààbò fún mi, ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà fún mi.


Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi, tí wọ́n sì ń pète ati pa mí; wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì.


Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́, nígbà tí àárẹ̀ mú mi. Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ,


Nígbà tí Farao súnmọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú sókè tí wọ́n rí àwọn ará Ijipti tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wọn; ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Wọ́n kígbe sí OLUWA;


ọgbọ́n inú yóo máa ṣọ́ ọ, òye yóo sì máa dáàbò bò ọ́,


Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ, nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ.


“Ẹ ṣe akiyesi pé mò ń ran yín lọ bí aguntan sáàrin ìkookò. Nítorí náà ẹ gbọ́n bí ejò, kí ẹ sì níwà tútù bí àdàbà.


Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣe lójo bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré wọnyi?” Ó bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati òkun wí, ìdákẹ́rọ́rọ́ ńlá bá dé.


Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ẹ lè ní alaafia nípa wíwà ninu mi. Ẹ óo ní ìpọ́njú ninu ayé, ṣugbọn ẹ ṣe ara gírí, mo ti ṣẹgun ayé.”


Wọ́n ń mú àwọn onigbagbọ lọ́kàn le pé kí wọ́n dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Wọ́n ń fi yé wọn pé kí eniyan tó wọ ìjọba Ọlọrun, ó níláti ní ọpọlọpọ ìṣòro.


ẹni tí ó ń fún wa ní ìwúrí ninu gbogbo ìpọ́njú tí à ń rí, kí àwa náà lè fi ìwúrí fún àwọn tí ó wà ninu oríṣìíríṣìí ìpọ́njú nípa ìwúrí tí àwa fúnra wa ti níláti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.


Wọn yóo ṣe inúnibíni sí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ gbé ìgbé-ayé olùfọkànsìn gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Inúnibíni níláti dé sí wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan