Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 32:6 - Yoruba Bible

6 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà pada wá jábọ̀ fún Jakọbu, wọ́n sọ fún un pé, “A jíṣẹ́ rẹ fún Esau arakunrin rẹ, ó sì ń bọ̀ wá pàdé rẹ pẹlu irinwo (400) ọkunrin.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Awọn onṣẹ si pada tọ̀ Jakobu wá, wipe, Awa dé ọdọ Esau, arakunrin rẹ, o si mbọ̀wá kò ọ, irinwo ọkunrin li o si wà pẹlu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jakọbu wà, wọ́n wí pé “Esau arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irínwó (400) ọkùnrin.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 32:6
14 Iomraidhean Croise  

Ó bẹ̀rẹ̀ sí da gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí ó ti kó jọ ní Padani-aramu siwaju, ó ń pada lọ sọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ní ilẹ̀ Kenaani.


Mo bẹ̀ ọ́, gbà mí lọ́wọ́ Esau arakunrin mi, nítorí ẹ̀rù rẹ̀ ń bà mí, kí ó má baà wá pa gbogbo wa, àtàwọn ìyá, àtàwọn ọmọ wọn.


Ẹ̀rù ba Jakọbu gidigidi, ó sì dààmú, ó bá dá àwọn eniyan tí wọn wà pẹlu rẹ̀ ati agbo mààlúù, ati agbo aguntan ati àwọn ràkúnmí rẹ̀ sí ọ̀nà meji meji.


Ó rò ninu ara rẹ̀ pé bí Esau bá dé ọ̀dọ̀ ìpín tí ó wà níwájú, tí ó bá sì pa wọ́n run, ìpín kan tí ó kù yóo sá àsálà.


Bí Jakọbu ti gbé ojú sókè, ó rí Esau tí ń bọ̀ pẹlu irinwo (400) ọkunrin. Ó bá pín àwọn ọmọ rẹ̀ fún Lea ati Rakẹli, ati àwọn iranṣẹbinrin mejeeji.


Esau bá ní, “Jẹ́ kí n fi àwọn bíi mélòó kan sílẹ̀ pẹlu rẹ ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi.” Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn pé, “Mo dúpẹ́, má wulẹ̀ ṣe ìyọnu kankan. Àní, kí n ṣá ti rí ojurere oluwa mi.”


Ó bá bèèrè, ó ní, “Kí ni o ti fẹ́ ṣe gbogbo àwọn agbo ẹran tí mo pàdé lọ́nà?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Mo ní kí n fi wọ́n wá ojurere Esau, oluwa mi ni.”


Ṣekemu tún wí fún baba ati àwọn arakunrin omidan náà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yọ́nú sí mi, ohunkohun tí ẹ bá ní kí n san, n óo san án.


Wọ́n dáhùn pé, “Ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ ikú, bí ó bá ti wù ọ́ bẹ́ẹ̀, a óo di ẹrú Farao.”


Yóo dàbí ìgbà tí eniyan ń sálọ fún kinniun, tí ó pàdé ẹranko beari lọ́nà; tabi tí ó sá wọ ilé rẹ̀, tí ó fọwọ́ ti ògiri, tí ejò tún bù ú jẹ.


Rutu bá dáhùn, ó ní, “O ṣàánú mi gan-an ni, oluwa mi, nítorí pé o ti tù mí ninu, o sì ti fi sùúrù bá èmi iranṣẹbinrin rẹ sọ̀rọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin rẹ.”


Ní ọjọ́ kan, Rutu sọ fún Naomi, ó ní, “Jẹ́ kí n lọ sí oko ẹnìkan, tí OLUWA bá jẹ́ kí n bá ojurere rẹ̀ pàdé, n ó máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọ́n ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀.” Naomi bá dá a lóhùn, ó ní, “Ó dára, máa lọ, ọmọ mi.”


Hana bá dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí èmi, iranṣẹbinrin rẹ, bá ojurere rẹ pàdé.” Ó bá dìde, ó jẹun, ó dárayá, kò sì banújẹ́ mọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan