Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 32:5 - Yoruba Bible

5 Ẹ ní mo ní àwọn mààlúù, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, agbo ẹran, àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin. Ẹ ní mo ní kí n kọ́ ranṣẹ láti sọ fún un ni, kí n lè rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Mo si ní malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agbo-ẹran, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin: mo si ranṣẹ wá wi fun oluwa mi, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 32:5
13 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu ṣe di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ó sì ní àwọn agbo ẹran ńláńlá, ọpọlọpọ iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin, ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.


Ti àwa ati àwọn ọmọ wa ni ohun ìní gbogbo tí Ọlọrun gbà lọ́wọ́ baba wa jẹ́, nítorí náà, gbogbo ohun tí Ọlọrun bá sọ fún ọ láti ṣe, ṣe é.”


Nígbà náà ni OLUWA sọ fún Jakọbu pé, “Pada lọ sí ilẹ̀ baba rẹ ati ti àwọn ìbátan rẹ, n óo sì wà pẹlu rẹ.”


Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá fún ọ nítorí pé Ọlọrun ti ṣe oore fún mi lọpọlọpọ ati pé mo ní ànító.” Jakọbu rọ̀ ọ́ títí tí ó fi gbà á.


Esau bá ní, “Jẹ́ kí n fi àwọn bíi mélòó kan sílẹ̀ pẹlu rẹ ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi.” Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn pé, “Mo dúpẹ́, má wulẹ̀ ṣe ìyọnu kankan. Àní, kí n ṣá ti rí ojurere oluwa mi.”


Ó bá bèèrè, ó ní, “Kí ni o ti fẹ́ ṣe gbogbo àwọn agbo ẹran tí mo pàdé lọ́nà?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Mo ní kí n fi wọ́n wá ojurere Esau, oluwa mi ni.”


Wọ́n dáhùn pé, “Ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ ikú, bí ó bá ti wù ọ́ bẹ́ẹ̀, a óo di ẹrú Farao.”


Ọba bá sọ fún Siba pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Mẹfiboṣẹti di tìrẹ láti ìsinsìnyìí lọ.” Siba sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, mo júbà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo.”


Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín? Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín, kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi?


Ṣugbọn bí ọmọ-ọ̀dọ̀ náà bá rò ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘Yóo pẹ́ kí oluwa mi tó dé,’ tí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, tí ó ń jẹ, tí ó ń mu, tí ó tún ń mutí yó,


Ní ọjọ́ kan, Rutu sọ fún Naomi, ó ní, “Jẹ́ kí n lọ sí oko ẹnìkan, tí OLUWA bá jẹ́ kí n bá ojurere rẹ̀ pàdé, n ó máa ṣa ọkà tí àwọn tí wọ́n ń kórè ọkà bá gbàgbé sílẹ̀.” Naomi bá dá a lóhùn, ó ní, “Ó dára, máa lọ, ọmọ mi.”


Hana bá dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí èmi, iranṣẹbinrin rẹ, bá ojurere rẹ pàdé.” Ó bá dìde, ó jẹun, ó dárayá, kò sì banújẹ́ mọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan