Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 32:4 - Yoruba Bible

4 Ó sọ fún wọn pé, “Ohun tí ẹ óo sọ fún Esau, oluwa mi nìyí, ẹ ní èmi, Jakọbu iranṣẹ rẹ̀, ní kí ẹ sọ fún un pé mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani, ati pé ibẹ̀ ni mo sì ti wà títí di àkókò yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 O si rán wọn wipe, Bayi ni ki ẹnyin ki o wi fun Esau, oluwa mi; Bayi ni Jakobu iranṣẹ rẹ wi, Mo ti ṣe atipo lọdọ Labani, mo si ti ngbé ibẹ̀ titi o fi di isisiyi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Esau olúwa mi, Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, ‘Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani títí ó fi di àsìkò yìí

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 32:4
23 Iomraidhean Croise  

“Gbọ́, oluwa wa, olóyè pataki ni o jẹ́ láàrin wa. Sin òkú aya rẹ síbikíbi tí ó bá wù ọ́ jùlọ ninu àwọn itẹ́ òkú wa, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wa tí kò ní fún ọ ní itẹ́ òkú rẹ̀, tabi tí yóo dí ọ lọ́wọ́, pé kí o má ṣe ohun tí o fẹ́ ṣe.”


Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jọ̀wọ́ fún mi jẹ ninu ẹ̀bẹ tí ó pupa yìí nítorí pé ebi ń pa mí kú lọ.” (Nítorí ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ṣe ń pè é ní Edomu.)


Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ. Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.”


Isaaki dá a lóhùn, ó ní, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ni mo sì ti fún un láti fi ṣe iranṣẹ, mo ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọkà ati ọtí waini. Kí ló tún wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?”


Ó di ogún ọdún tí mo ti dé ọ̀dọ̀ rẹ, mo fi ọdún mẹrinla sìn ọ́ nítorí àwọn ọmọbinrin rẹ, ati ọdún mẹfa fún agbo ẹran rẹ. Ìgbà mẹ́wàá ni o sì pa owó ọ̀yà mi dà.


Kí o wí pé, ‘Ti Jakọbu iranṣẹ rẹ ni, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn tí ó fi ranṣẹ sí Esau oluwa rẹ̀, òun alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ”


Ẹ ní mo ní àwọn mààlúù, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, agbo ẹran, àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin. Ẹ ní mo ní kí n kọ́ ranṣẹ láti sọ fún un ni, kí n lè rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ̀.”


Oluwa mi, máa lọ níwájú, n óo máa bọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ níwọ̀n bí ìrìn àwọn ẹran ati àwọn ọmọ bá ti lè yá mọ, títí tí n óo fi wá bá oluwa mi ní Seiri.”


Ó bá bèèrè, ó ní, “Kí ni o ti fẹ́ ṣe gbogbo àwọn agbo ẹran tí mo pàdé lọ́nà?” Jakọbu dáhùn, ó ní, “Mo ní kí n fi wọ́n wá ojurere Esau, oluwa mi ni.”


Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe di ẹni tí ń gbé orí òkè Seiri. Esau kan náà ni ń jẹ́ Edomu.


Àkọsílẹ̀ ìran Esau, baba àwọn ará Edomu, tí ń gbé orí òkè Seiri nìyí:


Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.”


Nítorí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, wọ́n sì wé okùn mọ́ ara wọn lórí. Wọ́n bá tọ Ahabu ọba lọ, wọ́n ní, “Benhadadi, iranṣẹ rẹ, ní kí á jíṣẹ́ fún ọ pé kí o jọ̀wọ́ kí o dá ẹ̀mí òun sí.” Ahabu bá dáhùn pé, “Ó ṣì wà láàyè? Arakunrin mi ni!”


Aaroni bá dáhùn, ó ní, “Má bínú, oluwa mi, ṣebí ìwọ náà mọ àwọn eniyan wọnyi pé eeyankeeyan ni wọ́n,


Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ a máa mú kí ibinu rọlẹ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ líle níí ru ibinu sókè.


Pẹlu sùúrù, a lè yí aláṣẹ lọ́kàn pada ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ eegun.


o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ. Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi, kí o lè gba ara rẹ là: lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́.


Bí aláṣẹ bá ń bínú sí ọ, má ṣe torí rẹ̀ kúrò ní ìdí iṣẹ́ rẹ, ìtẹríba lè mú kí wọn dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá tóbi jini.


Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Edomu nìyí: Ẹnìkan ń pè mí láti Seiri Ó ní: “Aṣọ́nà, Òru ti rí o? Aṣọ́nà, àní òru ti rí?”


Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”


Irú wọn ni Sara tí ó gbọ́ràn sí Abrahamu lẹ́nu tí ó pè é ní “Oluwa mi.” Ọmọ Sara ni yín, tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ kò jẹ́ kí nǹkankan bà yín lẹ́rù tabi kí ó mú ìpayà ba yín.


OLUWA, nígbà tí o jáde lọ láti òkè Seiri, nígbà tí o jáde lọ láti agbègbè Edomu, ilẹ̀ mì tìtì, omi bẹ̀rẹ̀ sí bọ́, ọ̀wààrà òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀.


Saulu mọ̀ pé Dafidi ni ó ń sọ̀rọ̀, ó bá bèèrè pé, “Dafidi ọmọ mi, ṣé ìwọ ni ò ń sọ̀rọ̀?” Dafidi dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan