Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 32:2 - Yoruba Bible

2 Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó ní, “Àwọn ọmọ ogun Ọlọrun nìyí.” Ó bá sọ ibẹ̀ ní Mahanaimu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Nigbati Jakobu si ri wọn, o ni, Ogun Ọlọrun li eyi: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Mahanaimu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó wí pé, “Àgọ́ Ọlọ́run ni èyí!” Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ni Mahanaimu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 32:2
17 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ré odò Jọdani kọjá tán, Dafidi ti dé ìlú tí wọn ń pè ní Mahanaimu.


Abineri ọmọ Neri ati àwọn iranṣẹ Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ṣígun láti Mahanaimu, lọ sí ìlú Gibeoni.


Abineri ọmọ Neri, tíí ṣe balogun àwọn ọmọ ogun Saulu, gbé Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu sá lọ sí Mahanaimu ní òdìkejì odò Jọdani.


“Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ṣimei ọmọ Gera ará Bahurimu láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, èpè burúkú ni ó ń gbé mi ṣẹ́ lemọ́lemọ́ ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Ṣugbọn nígbà tí ó wá pàdé mi létí odò Jọdani, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un ní orúkọ OLUWA pé, n kò ní pa á.


Ahinadabu, ọmọ Ido ni alákòóso agbègbè Mahanaimu.


Eliṣa bá gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ ṣí ojú rẹ̀, kí ó lè ríran. OLUWA ṣí iranṣẹ náà lójú, ó sì rí i pé gbogbo orí òkè náà kún fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, iná sí yí Eliṣa ká.


Lojoojumọ ni àwọn eniyan ń wá sọ́dọ̀ Dafidi láti ràn án lọ́wọ́; títí tí wọ́n fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n dàbí ogun ọ̀run.


Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.


Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀; ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀.


Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA àwọn ọmọ ogun, òun ni Ọba ògo náà.


Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, a sì máa gbà wọ́n.


Máa pada bọ̀, máa pada bọ̀, ìwọ ọmọbinrin ará Ṣulamu. Máa pada bọ̀, kí á lè máa fi ọ́ ṣe ìran wò. Ẹ óo ṣe máa fi ará Ṣulamu ṣe ìran wò bí ẹni wo ẹni tí ó ń jó níwájú ọ̀wọ́ ọmọ ogun meji?


Ó bi mí pé, “Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Nisinsinyii n óo pada lọ bá aláṣẹ ìjọba Pasia jà, tí mo bá bá a jà tán, aláṣẹ ìjọba Giriki yóo wá.


Lójijì ọpọlọpọ àwọn ogun ọ̀run yọ pẹlu angẹli náà, wọ́n ń yin Ọlọrun pé,


Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi, wọ́n fún wọn ní: Ramoti ní Gileadi. Ramoti yìí ni ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan. Wọ́n tún fún wọn ní Mahanaimu,


Ọkunrin náà dáhùn pé, “Rárá, mo wá gẹ́gẹ́ bíi balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA ni.” Joṣua bá dojúbolẹ̀, ó sin OLUWA, ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe, OLUWA mi?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan