Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 3:3 - Yoruba Bible

3 àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ṣugbọn ninu eso igi nì ti o wà lãrin ọgbà Ọlọrun ti wipe, Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ fọwọkàn a, ki ẹnyin ki o má ba kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èso igi tí ó wà láàrín ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kùú.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 3:3
12 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun dá a lóhùn lójú àlá, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé òtítọ́ inú ni o fi ṣe ohun tí o ṣe, èmi ni mo sì pa ọ́ mọ́ tí n kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ mí, ìdí sì nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án.


Obinrin náà dá a lóhùn, ó ní: “A lè jẹ ninu èso àwọn igi tí wọ́n wà ninu ọgbà,


Ṣugbọn ejò náà dáhùn, ó ní, “Ẹ kò ní kú rárá,


Ó ní, “Ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi, ẹ má sì pa àwọn wolii mi lára!”


Ǹjẹ́, ìwọ mú gbogbo nǹkan wọnyi kúrò wò, o óo rí i pé yóo sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.”


Ẹ ṣàánú mi, ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọrun ti bà mí!


Ìwọ fi ọwọ́ kan ara ati eegun rẹ̀ wò, bí kò bá ní sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.”


Ọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí ẹ kọ nípa rẹ̀, ó dára tí ọkunrin bá lè ṣe é kí ó má ní obinrin rara.


Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí. Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́, kí n lè gbà yín.


“Má fọwọ́ kan èyí,” “Má jẹ tọ̀hún,” “Má ṣegbá, má ṣàwo?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan