Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 2:9 - Yoruba Bible

9 Láti inú ilẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun ti mú kí oríṣìíríṣìí igi hù jáde ninu ọgbà náà, tí wọ́n dùn ún wò, tí wọ́n sì dára fún jíjẹ. Igi ìyè wà láàrin ọgbà náà, ati igi ìmọ̀ ibi ati ire.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Lati inu ilẹ li OLUWA Ọlọrun mu onirũru igi hù jade wá, ti o dara ni wiwò, ti o si dara fun onjẹ; ìgi ìye pẹlu lãrin ọgbà na, ati igi ìmọ rere ati buburu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀: àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 2:9
19 Iomraidhean Croise  

ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso igi ìmọ̀ ibi ati ire. Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ ni o óo kú.”


Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.”


Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún.


àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.”


Ọlọrun sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé bí ẹ bá jẹ ẹ́, ojú yín yóo là, ẹ óo sì dàbí òun alára, ẹ óo mọ ire yàtọ̀ sí ibi.”


Èso olódodo ni igi ìyè, ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan.


Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn, ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin.


èmi tí mo sọ àmì àwọn tí ń woṣẹ́ èké di asán, tí mo sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀. Mo yí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n po mo sì sọ ọgbọ́n wọn di òmùgọ̀.


“Ọkàn rẹ balẹ̀ ninu iṣẹ́ ibi rẹ, o ní ẹnìkan kò rí ọ. Ọgbọ́n ati ìmọ̀ rẹ mú ọ ṣìnà, ò ń sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Èmi nìkan ní mo wà. Kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’


Ìró wíwó rẹ̀ yóo mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. Nígbà tí mo bá wó o lulẹ̀ tí mo bá sọ ọ́ sinu isà òkú pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú; gbogbo àwọn igi Edẹni, ati àwọn igi tí wọ́n dára jù ní Lẹbanoni, gbogbo àwọn igi tí ń rí omi mu lábẹ́ ilẹ̀ ni ara yóo tù.


“Ògo ati títóbi ta ni a lè fi wé tìrẹ láàrin àwọn igi tí ó wà ní Edẹni? Ṣugbọn a óo gé ọ lulẹ̀ pẹlu àwọn igi ọgbà Edẹni, a óo sì wọ́ ọ sọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. O óo wà nílẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí a fi idà pa. Farao ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ni mò ń sọ nípa wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Oríṣìíríṣìí igi eléso yóo hù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji odò náà: ewé àwọn igi náà kò ní rọ, bẹ́ẹ̀ ni èso wọn kò ní tán. Lóṣooṣù ni wọn yóo máa so èso tuntun nítorí pé láti inú tẹmpili ni omi rẹ̀ yóo ti máa sun jáde wá. Èso wọn yóo wà fún jíjẹ, ewé wọn yóo sì wà fún ìwòsàn.”


Èmi pàápàá ni oúnjẹ tí ó ń fún eniyan ní ìyè.


Ó wá kan ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a fi rúbọ fún oriṣa. A mọ̀ pé, “Gbogbo wa ni a ní ìmọ̀,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn irú ìmọ̀ yìí a máa mú kí eniyan gbéraga, ṣugbọn ìfẹ́ ní ń mú kí eniyan dàgbà.


A óo kà wá sí olódodo bí a bá pa gbogbo àwọn òfin wọnyi mọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun wa, bí ó ti pa á láṣẹ fún wa.’


“Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. “Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni n óo fún ní àṣẹ láti jẹ ninu èso igi ìyè tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun.


Àwọn tí wọ́n bá fọ aṣọ wọn ṣe oríire. Wọn óo ní àṣẹ láti dé ibi igi ìyè, wọn óo sì gba ẹnu ọ̀nà wọ inú ìlú mímọ́ náà.


Ó gba ààrin títì ìlú náà. Igi ìyè kan wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ òsì odò náà. Igi ìyè yìí ń so èso mejila, ọ̀kan ní oṣooṣù. Ewé igi náà wà fún ìwòsàn àwọn orílẹ̀-èdè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan