Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 2:8 - Yoruba Bible

8 OLUWA Ọlọrun ṣe ọgbà kan sí Edẹni, ní ìhà ìlà oòrùn, ó fi eniyan tí ó mọ sinu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 OLUWA Ọlọrun si gbìn ọgbà kan niha ìla-õrùn ni Edeni; nibẹ̀ li o si fi ọkunrin na ti o ti mọ si.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 2:8
12 Iomraidhean Croise  

Lọti bá gbójú sókè, ó wo gbogbo agbègbè odò Jọdani títí dé Soari, ó rí i pé gbogbo koríko ibẹ̀ ni wọ́n tutù dáradára tí ó dàbí ọgbà OLUWA ati bí ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, OLUWA kò tíì pa ìlú Sodomu ati Gomora run.


Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde.


Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún.


Kaini bá kúrò níwájú OLUWA, ó lọ ń gbé ìlú tí ń jẹ́ Nodu. Ó wà ní apá ìlà oòrùn ọgbà Edẹni.


Àwọn baba ńlá mi ti pa àwọn ìlú Gosani, Harani, Resefu ati àwọn ọmọ Edẹni tí wọ́n wà ní Telasari run, àwọn ọlọrun wọn kò sì lè gbà wọ́n.


“OLUWA yóo tu Sioni ninu, yóo tu gbogbo àwọn tí ó ṣòfò ninu rẹ̀ ninu; yóo sì sọ aṣálẹ̀ rẹ̀ dàbí Edẹni, ọgbà OLUWA. Ayọ̀ ati ìdùnnú ni yóo máa wà ninu rẹ̀, pẹlu orin ọpẹ́ ati orin ayọ̀.


Àwọn ará Harani, Kane, Edẹni, Aṣuri ati Kilimadi ń bá ọ ṣòwò.


O wà ninu Edẹni, ọgbà Ọlọrun. Gbogbo òkúta olówó iyebíye ni wọ́n fi ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òkúta bíi: kaneliani, topasi, ati jasiperi; kirisolite, bẹrili, ati onikisi; safire, kabọnku ati emeradi. A gbé ọ ka inú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí a ṣe fún ọ ní ọjọ́ tí a dá ọ.


Ìró wíwó rẹ̀ yóo mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. Nígbà tí mo bá wó o lulẹ̀ tí mo bá sọ ọ́ sinu isà òkú pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú; gbogbo àwọn igi Edẹni, ati àwọn igi tí wọ́n dára jù ní Lẹbanoni, gbogbo àwọn igi tí ń rí omi mu lábẹ́ ilẹ̀ ni ara yóo tù.


“Ògo ati títóbi ta ni a lè fi wé tìrẹ láàrin àwọn igi tí ó wà ní Edẹni? Ṣugbọn a óo gé ọ lulẹ̀ pẹlu àwọn igi ọgbà Edẹni, a óo sì wọ́ ọ sọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. O óo wà nílẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí a fi idà pa. Farao ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ni mò ń sọ nípa wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Iná ń jó àjórun níwájú wọn, ahọ́n iná ń yọ lálá lẹ́yìn wọn. Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edẹni níwájú wọn, ṣugbọn lẹ́yìn wọn, ó dàbí aṣálẹ̀ tí ó ti di ahoro, kò sì sí ohun tí yóo bọ́ lọ́wọ́ wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan