Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 2:7 - Yoruba Bible

7 Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ enia; o si mí ẹmí ìye si ihò imu rẹ̀; enia si di alãye ọkàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 2:7
33 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn.


Ṣugbọn omi kan a máa ru jáde láti inú ilẹ̀ láti mú kí gbogbo ilẹ̀ rin.


Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ, títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀, nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá. Erùpẹ̀ ni ọ́, o óo sì pada di erùpẹ̀.”


Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde.


Gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń mí lórí ilẹ̀ ayé patapata ni wọ́n kú.


níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, tí mo sì ń mí,


Ẹ̀mí Ọlọrun ni ó dá mi, èémí Olodumare ni ó sì fún mi ní ìyè.


Wò ó, bákan náà ni èmi pẹlu rẹ rí lójú Ọlọrun, amọ̀ ni a fi mọ èmi náà.


mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ, tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀, tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn.


Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun, òun ló dá wa, òun ló ni wá; àwa ni eniyan rẹ̀, àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀.


Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa; ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá.


Ẹ̀mí eniyan ni fìtílà OLUWA, tíí máa wá gbogbo kọ́lọ́fín inú rẹ̀ kiri.


kí erùpẹ̀ tó pada sí ilẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀mí tó pada tọ Ọlọrun tí ó fúnni lọ.


Àkókò fífa nǹkan ya wà, àkókò rírán nǹkan pọ̀ sì wà; àkókò dídákẹ́ wà, àkókò ọ̀rọ̀ sísọ sì wà.


Ẹ má gbẹ́kẹ̀lé eniyan mọ́. Ẹlẹ́mìí ni òun alára, nítorí pé kí ni ó lè ṣe?


Sibẹsibẹ OLUWA, ìwọ ni baba wa, amọ̀ ni wá, ìwọ sì ni amọ̀kòkò; iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni gbogbo wa.


Ẹ̀mí àwa ẹni àmì òróró OLUWA bọ́ sinu kòtò wọn, OLUWA tí à ń sọ nípa rẹ̀ pé, lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni a óo máa gbé láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.


Ó ní: ‘N óo mú kí èémí wọ inú yín, ẹ óo sì di alààyè.


N óo fi iṣan bò yín lára; lẹ́yìn náà n óo fi ara ẹran bò yín, n óo sì da awọ bò yín lára. N óo wá fi èémí si yín ninu, ẹ óo di alààyè, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”


Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí Israẹli nìyí, OLUWA tí ó ta ọ̀run bí aṣọ, tí ó dá ayé, tí ó sì dá ẹ̀mí sinu eniyan, ni ó sọ báyìí pé,


Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀, wọ́n gbadura sí OLUWA, pé, “Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè, ìwọ yóo ha tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan bínú sí gbogbo ìjọ eniyan bí?”


“OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè gbogbo nǹkan alààyè. Èmi bẹ̀ ọ́, yan ẹnìkan tí yóo máa ṣáájú àwọn eniyan wọnyi:


Lẹ́yìn tí ó sọ bẹ́ẹ̀ tán, ó mí sí wọn, ó bá wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́.


bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí kò ní, tí a óo sọ pé kí eniyan fún un, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó ń fún gbogbo eniyan ní ẹ̀mí, èémí ati ohun gbogbo.


Ṣugbọn ta ni ọ́, ìwọ ọmọ-eniyan, tí o fi ń gbó Ọlọrun lẹ́nu? Ǹjẹ́ ìkòkò lè wí fún ẹni tí ó ń mọ ọ́n pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí?”


Ó wà ninu àkọsílẹ̀ pé, “Adamu, ọkunrin àkọ́kọ́ di alààyè;” ṣugbọn Adamu ìkẹyìn jẹ́ ẹ̀mí tí ó ń sọ eniyan di alààyè.


Ọkunrin kinni tí a fi erùpẹ̀ dá jẹ́ erùpẹ̀, láti ọ̀run ni ọkunrin keji ti wá.


Ṣugbọn bí ìkòkò amọ̀ ni àwa tí ìṣúra yìí wà ninu wa rí, kí ó lè hàn gbangba pé Ọlọrun ni ó ní agbára tí ó tóbi jùlọ, kì í ṣe àwa.


Nítorí a mọ̀ pé bí àgọ́ ara tí a fi ṣe ilé ní ayé yìí bá wó, a ní ilé kan lọ́dọ̀ Ọlọrun, tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí yóo wà lọ́run títí laelae.


Nítorí Adamu ni a kọ́kọ́ dá, kí á tó dá Efa.


Ṣebí a ní àwọn baba tí wọ́n bí wa, tí wọn ń tọ́ wa sọ́nà, tí a sì ń bu ọlá fún wọn. Báwo ni ó wá yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún Baba wa nípa ti ẹ̀mí tó, kí á sì ní ìyè?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan