Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 2:5 - Yoruba Bible

5 kò tíì sí ohun ọ̀gbìn kankan lórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ewéko kankan kò tíì hù jáde nítorí pé OLUWA Ọlọrun kò tíì rọ òjò sórí ilẹ̀, kò sì tíì sí eniyan láyé tí yóo máa ro ilẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ati olukuluku igi igbẹ ki o to wà ni ilẹ, ati olukuluku eweko igbẹ ki nwọn ki o to hù: OLUWA Ọlọrun kò sa ti rọ̀jo si ilẹ, kò si sí enia kan lati ro ilẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 2:5
15 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn omi kan a máa ru jáde láti inú ilẹ̀ láti mú kí gbogbo ilẹ̀ rin.


Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde.


Láti òní lọ, nígbà tí o bá dá oko, ilẹ̀ kò ní fi gbogbo agbára rẹ̀ so èso fún ọ mọ́, ìsáǹsá ati alárìnká ni o óo sì jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.”


Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkunrin mìíràn, ó sọ ọ́ ní Abeli. Iṣẹ́ darandaran ni Abeli ń ṣe, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.


A máa rọ òjò sórí ilẹ̀, a sì máa bomi rin oko.


Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ, ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan, kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀;


Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé, ó fi mànàmáná fún òjò, ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.


Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé, tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀, tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ.


Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run, ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé, òun ni ó dá mànàmáná fún òjò, tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.


Ninu gbogbo àwọn ọlọrun èké tí àwọn orílẹ̀-èdè ń sìn, ǹjẹ́ ọ̀kan wà tí ó lè mú kí òjò rọ̀? Àbí ojú ọ̀run ní ń fúnrarẹ̀ rọ ọ̀wààrà òjò? OLUWA Ọlọrun wa, ṣebí ìwọ ni? Ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé, nítorí ìwọ ni o ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.


Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ti di ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. Nítorí a máa mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere; a sì máa rọ òjò sórí àwọn olódodo ati sórí àwọn alaiṣododo.


Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan