Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 2:3 - Yoruba Bible

3 Ó súre fún ọjọ́ keje yìí, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ọjọ́ náà ni ó sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe bọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ọlọrun si busi ijọ́ keje, o si yà a si mimọ́; nitori pe, ninu rẹ̀ li o simi kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti bẹ̀rẹ si iṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 2:3
22 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun wo gbogbo ohun tí ó dá, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹfa.


Ní ọjọ́ keje, Ọlọrun parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ náà.


Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe dá ọ̀run ati ayé. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé,


O kọ́ wọn láti máa pa ọjọ́ ìsinmi rẹ mọ́, o sì tún pèsè ẹ̀kọ́, ìlànà, ati òfin fún wọn láti ọwọ́ Mose iranṣẹ rẹ.


“Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ní ọjọ́ keje, kí o sinmi; àtìwọ ati akọ mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ; kí ara lè tu ọmọ iranṣẹbinrin rẹ ati àlejò rẹ.


“Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣe iṣẹ́ yín, ní ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ sinmi; kì báà ṣe àkókò oko ríro, tabi àkókò ìkórè, dandan ni kí ẹ sinmi.


Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là, kì í sì í fi làálàá kún un.


Lẹ́yìn náà, mo fún wọn ní ọjọ́ ìsinmi, kí ó máa jẹ́ àmì láàrin èmi pẹlu wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi OLUWA yà wọ́n sí mímọ́.


Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, ati ọjọ́ ìpéjọ mímọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, ọjọ́ ìsinmi ni fún OLUWA ní gbogbo ibùgbé yín.


Ó wá wí fún wọn pé, “Lílò eniyan ni a dá Ọjọ́ Ìsinmi fún, a kò dá eniyan fún Ọjọ́ Ìsinmi.


Wọ́n bá pada lọ láti lọ tọ́jú turari olóòórùn dídùn ati ìpara tí wọn fi ń tọ́jú òkú. Ní Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n sinmi gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan