Gẹnẹsisi 2:2 - Yoruba Bible2 Ní ọjọ́ keje, Ọlọrun parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ náà. Faic an caibideilBibeli Mimọ2 Ni ijọ́ keje Ọlọrun si pari iṣẹ rẹ̀ ti o ti nṣe; o si simi ni ijọ́ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo ti o ti nṣe. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. Faic an caibideil |
ṣugbọn ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA Ọlọrun rẹ. Ní ọjọ́ náà, o kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati àwọn ọmọ rẹ obinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ, ati mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àlejò tí ń gbé ilẹ̀ rẹ; kí iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin rẹ lè sinmi bí ìwọ náà ti sinmi.