Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 16:3 - Yoruba Bible

3 Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti dé ilẹ̀ Kenaani ni Sarai, aya rẹ̀ fa Hagari, ará Ijipti, ẹrubinrin rẹ̀ fún un, láti fi ṣe aya.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Sarai, aya Abramu, si mu Hagari ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ ara Egipti na, lẹhin igbati Abramu gbé ilẹ Kenaani li ọdún mẹwa, o si fi i fun Abramu ọkọ rẹ̀ lati ma ṣe aya rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 16:3
15 Iomraidhean Croise  

Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹrindinlaadọrun nígbà tí Hagari bí Iṣimaeli fún un.


Abramu bá Hagari lòpọ̀, Hagari sì lóyún. Nígbà tí ó rí i pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú tẹmbẹlu Sarai, oluwa rẹ̀.


Sarai bá sọ fún Abramu pé, “Ibi tí Hagari ń ṣe sí mi yìí yóo dà lé ọ lórí. Èmi ni mo fa ẹrubinrin mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó rí i pé òun lóyún tán, mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lójú rẹ̀. OLUWA ni yóo ṣe ìdájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ.”


Ó ń gbé inú aginjù Parani, ìyá rẹ̀ sì fẹ́ aya fún un ní ilẹ̀ Ijipti.


Ẹ̀bùn ni ó fún gbogbo ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn bí fún un, kí ó tó kú ni ó sì ti ní kí wọ́n jáde kúrò lọ́dọ̀ Isaaki, kí wọ́n lọ máa gbé ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ náà.


Nítorí náà Esau lọ sọ́dọ̀ Iṣimaeli ọmọ Abrahamu, ó sì fẹ́ Mahalati ọmọ rẹ̀, tíí ṣe arabinrin Nebaiotu, ó fi kún àwọn aya tí ó ti ní.


Ó bá fún Jakọbu ní Biliha, iranṣẹbinrin rẹ̀ kí ó fi ṣe aya, Jakọbu sì bá a lòpọ̀.


Nígbà tí Lea rí i pé òun kò bímọ mọ́, ó fún Jakọbu ní Silipa, iranṣẹbinrin rẹ̀, kí ó fi ṣe aya.


Ní òru ọjọ́ náà gan an, ó dìde ó kó àwọn aya rẹ̀ mejeeji, àwọn iranṣẹbinrin mejeeji ati àwọn ọmọ rẹ̀ mọkọọkanla, ó kọjá sí ìhà keji odò Jaboku.


Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀.


Nígbà tí Dafidi kúrò ní Heburoni lọ sí Jerusalẹmu, ó fẹ́ àwọn obinrin mìíràn kún àwọn aya rẹ̀. Ó sì ní ọpọlọpọ ọmọ sí i, lọkunrin ati lobinrin.


Ẹẹdẹgbẹrin (700) ni àwọn obinrin ati ọmọ ọba tí Solomoni gbé níyàwó, ó sì tún ní ọọdunrun (300) obinrin mìíràn. Àwọn obinrin náà sì mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun.


Hagari ni òkè Sinai ní Arabia tíí ṣe àpẹẹrẹ Jerusalẹmu ti òní. Ó wà ninu ipò ẹrú pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan