Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 13:4 - Yoruba Bible

4 láàrin Bẹtẹli ati Ai, níbi pẹpẹ tí ó kọ́kọ́ pa, ibẹ̀ ni ó sì ti sin OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Si ibi pẹpẹ ti o ti tẹ́ nibẹ̀ ni iṣaju: nibẹ̀ li Abramu si nkepè orukọ OLUWA.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 13:4
21 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà, Abramu kó àgọ́ rẹ̀ wá sí ibi igi Oaku ti Mamure, tí ó wà ní Heburoni, níbẹ̀ ni ó ti tẹ́ pẹpẹ fún OLUWA.


Ó bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan sibẹ.


Seti bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Enọṣi. Nígbà náà ni àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn ní orúkọ mímọ́ OLUWA.


Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.


Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún eniyan.


Jẹ́ kí wọn máa yin OLUWA nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, àní nítorí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe fún àwọn ọmọ eniyan.


N óo rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ, n óo sì pe orúkọ rẹ OLUWA.


Nítorí pé ó tẹ́tí sí mi, nítorí náà, n óo máa ké pè é níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.


OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é, àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn.


OLUWA, mo fẹ́ràn ilé rẹ, tí ò ń gbé, ati ibi tí ògo rẹ wà.


Nítorí pé ọjọ́ kan péré ninu àgbàlá rẹ, ṣe anfaani ju ẹgbẹrun ọjọ́ níbòmíràn lọ. Ó wù mí kí n jẹ́ aṣọ́nà ninu ilé Ọlọrun mi ju pé kí n máa gbé inú àgọ́ àwọn eniyan burúkú.


Ẹ óo ké pè mí nígbà náà, n óo sì da yín lóhùn. Ẹ óo kígbe pè mí, n óo sì dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’ “Bí ẹ bá mú àjàgà kúrò láàrin yín, tí ẹ kò fi ìka gún ara yín nímú mọ́, tí ẹ kò sì sọ ọ̀rọ̀ ibi mọ́.


Ẹ óo ké pè mí, ẹ óo gbadura sí mi, n óo sì gbọ́ adura yín.


“N óo wá yí ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pada nígbà náà, yóo sì di mímọ́, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ èmi OLUWA, kí wọ́n sì sìn mí pẹlu ọkàn kan.


Sí ìjọ Ọlọrun ti ó wà ní Kọrinti, àwọn tí a yà sí mímọ́ nípa ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀, ati gbogbo àwọn tí ń pe orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi níbi gbogbo, Jesu tíí ṣe Oluwa tiwọn ati tiwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan