Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 13:2 - Yoruba Bible

2 Abramu ní dúkìá pupọ ní àkókò yìí, ó ní ẹran ọ̀sìn, fadaka ati wúrà lọpọlọpọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Abramu si là gidigidi, li ẹran-ọ̀sin, ni fadaka, ati ni wurà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 13:2
17 Iomraidhean Croise  

Nítorí ti Sarai, Farao ṣe Abramu dáradára. Abramu di ẹni tí ó ní ọpọlọpọ aguntan, akọ mààlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, iranṣẹkunrin, iranṣẹbinrin, abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí.


Ẹran ọ̀sìn àwọn mejeeji pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ náà kò fi láàyè tó mọ́ fún wọn láti jọ máa gbé pọ̀.


Abrahamu ti darúgbó, Ọlọrun sì ti bukun un ní gbogbo ọ̀nà.


OLUWA ti bukun oluwa mi lọpọlọpọ, ó sì ti di eniyan ńlá. OLUWA ti fún un ní ọpọlọpọ mààlúù ati agbo ẹran, ọpọlọpọ fadaka ati wúrà, ọpọlọpọ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ati ọpọlọpọ ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.


Ó ní ọpọlọpọ agbo aguntan ati agbo mààlúù, pẹlu ọpọlọpọ iranṣẹ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Filistia bẹ̀rẹ̀ sí jowú rẹ̀.


Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu ṣe di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ó sì ní àwọn agbo ẹran ńláńlá, ọpọlọpọ iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin, ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.


Ṣebí nígbà gbogbo ni ò ń dáàbò bo òun ati àwọn ará ilé rẹ̀, ati gbogbo ohun tí ó ní. Ò ń bukun iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, o sì sọ ohun ìní rẹ̀ di pupọ.


Ó ní ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan, ẹgbẹẹdogun (3,000) ràkúnmí, ẹẹdẹgbẹta (500) àjàgà mààlúù, ẹẹdẹgbẹta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati ọpọlọpọ iranṣẹ; òun ni ó lọ́lá jùlọ ninu gbogbo àwọn ará ìlà oòrùn.


Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là, kì í sì í fi làálàá kún un.


Ṣugbọn ẹ kọ́kọ́ máa wá ìjọba Ọlọrun ná ati òdodo rẹ̀, gbogbo nǹkan wọnyi ni a óo fi kún un fún yín.


Ẹ ranti OLUWA Ọlọrun yín nítorí òun ni ó fun yín ní agbára láti di ọlọ́rọ̀, kí ó lè fìdí majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba yín dá múlẹ̀, bí ó ti rí lónìí.


Eniyan a máa rí anfaani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá ti ara, ṣugbọn anfaani ti ẹ̀mí kò lópin; nítorí ó ní anfaani ní ayé yìí, ó tún fún eniyan ní anfaani ti ayé tí ń bọ̀.


OLUWA ni ó lè sọni di aláìní, òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀. Òun ni ó ń gbéni ga, òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan