Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 13:1 - Yoruba Bible

1 Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde kúrò ní Ijipti, ó pada lọ sí Nẹgẹbu pẹlu aya rẹ̀, ati Lọti ati ohun gbogbo tí ó ní.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 ABRAMU si goke lati Egipti wá, on, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ati Loti pẹlu rẹ̀, si ìha gusu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 13:1
8 Iomraidhean Croise  

Láti ibẹ̀ ni Abrahamu ti lọ sí agbègbè Nẹgẹbu, ó sì ń gbé Gerari, ní ààrin Kadeṣi ati Ṣuri.


Abrahamu gbin igi tamarisiki kan sí Beeriṣeba, ó sì ń sin OLUWA Ọlọrun ayérayé níbẹ̀.


Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí apá gúsù. Wọ́n dé ìlú olódi ti Tire, títí lọ dé gbogbo ìlú àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Kenaani. Níkẹyìn, wọ́n wá sí Beeriṣeba ní apá ìhà gúsù Juda.


Mose rán wọn láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà. Kí wọ́n tó lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà ìhà àríwá, kí ẹ tọ̀ ọ́ lọ sí ìhà gúsù ilẹ̀ Kenaani, kí ẹ wá lọ sí àwọn orí òkè.


Joṣua ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ náà, ati àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè, ati àwọn tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Nẹgẹbu ní apá gúsù, ati àwọn tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ati gbogbo àwọn ọba wọn. Kò dá ẹnikẹ́ni sí, gbogbo wọn patapata ni ó parun gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli pa fún un.


Ọ̀nà meje ni wọn yóo pín ilẹ̀ náà sí, àwọn ẹ̀yà Juda kò ní kúrò ní àyè tiwọn ní apá ìhà gúsù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀yà Josẹfu tí wọ́n wà ní agbègbè tiwọn ní apá ìhà àríwá.


Bí Akiṣi bá bèèrè pé, “Àwọn wo ni ẹ kógun lọ bá lónìí?” Dafidi á sì dáhùn pé, “Ìhà gúsù Juda ni, tabi kí ó sọ wí pé ìhà gúsù Jerameeli tabi ìhà gúsù Keni.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan