Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 1:1 - Yoruba Bible

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 Ní atetekọṣe Ọlọrun dá ọrun ati aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 1:1
67 Iomraidhean Croise  

Ó gbadura pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ń gbé láàrin àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun tí ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ìwọ ni o dá ayé ati ọ̀run.


Nítorí pé ère lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù sọ di ọlọrun, ṣugbọn OLUWA ló dá ọ̀run.


Huramu, ọba Tire, bá dá èsì lẹta Solomoni pada, ó ní, “OLUWA fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀, ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn.”


Ẹsira ní: “Ìwọ nìkan ni OLUWA, ìwọ ni o dá ọ̀run, àní, ọ̀run tí ó ga jùlọ, ati gbogbo àwọn ìràwọ̀ tí ó wà lójú ọ̀run, ìwọ ni o dá ilé ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, ati àwọn òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn. Ìwọ ni o mú kí gbogbo wọn wà láàyè, ìwọ sì ni àwọn ogun ọ̀run ń sìn.


Ó fi afẹ́fẹ́ ṣe ojú ọ̀run lọ́ṣọ̀ọ́; ọwọ́ ló fi pa ejò tí ń fò.


Níbo lo wà, nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Bí o bá mọ ìgbà náà, sọ fún mi.


òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ, tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀.


Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run.


OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn. Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ.


Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde, wọ́n di ẹ̀dá alààyè, o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun.


Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun yín!


Ìrànlọ́wọ́ mi ń ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé.


Ọ̀dọ̀ OLUWA ni ìrànlọ́wọ́ wa ti wá, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé.


Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun yín láti Sioni wá.


Ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;


Ọlọrun tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀; Ọlọrun tíí máa ń pa àdéhùn rẹ̀ mọ́ títí lae,


Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run, èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀.


Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà; ó pàṣẹ, ayé sì dúró.


Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀–


Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀? Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀?


Kí o tó dá àwọn òkè, ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé, láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun.


Nítorí oriṣa lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń sìn, ṣugbọn OLUWA ni ó dá ọ̀run.


Nítorí pé, ọjọ́ mẹfa ni èmi OLUWA fi dá ọ̀run ati ayé, ati òkun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn; mo sì sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni mo ṣe bukun ọjọ́ ìsinmi náà, tí mo sì yà á sí mímọ́.


Nígbà tí Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀ tán lórí òkè Sinai, ó fún un ní wàláà òkúta meji gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ọlọrun fúnra rẹ̀ ni ó fi ìka ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára àwọn wàláà náà.


OLUWA a máa jẹ́ kí ohun gbogbo yọrí sí bí ó bá ti fẹ́, ó dá eniyan burúkú fún ọjọ́ ìyọnu.


Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀, òye ni ó sì fi dá ọ̀run.


Ranti ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ, kí ọjọ́ ibi tó dé, kí ọjọ́ ogbó rẹ tó súnmọ́ etílé, nígbà tí o óo wí pé, “N kò ní inú dídùn ninu wọn.”


“Ìwọ OLUWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israẹli, ìwọ tí ìtẹ́ rẹ wà lórí àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun gbogbo ìjọba ayé, ìwọ ni ó sì dá ọ̀run ati ayé.


Ṣé ẹ kò tíì mọ̀? Ẹ kò sì tíì gbọ́? Ṣé wọn kò sọ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀, kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé:


Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run, ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi? Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun, tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan, tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀. Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó, ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó, ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì.


Ṣé o kò tíì mọ̀, o kò sì tíì gbọ́ pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA, Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé. Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a. Àwámárìídìí ni òye rẹ̀.


Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ; ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ, tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀; ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀; tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀.


Gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà rẹ wí, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú oyún. Ó ní, “Èmi ni OLUWA, tí mo dá ohun gbogbo. Èmi nìkan ni mo tẹ́ ojú ọ̀run, tí mo sì dá ilẹ̀ ayé tẹ́,


Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, OLUWA tí ó dá ọ̀run. (Òun ni Ọlọrun.) Òun ni ó dá ilẹ̀, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò dá a ninu rúdurùdu, ṣugbọn ó dá a kí eniyan lè máa gbé inú rẹ̀ Ó ní, “Èmi ni OLUWA, kò sí Ọlọrun mìíràn.


O gbàgbé OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ, tí ó ta ojú ọ̀run bí aṣọ, tí ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀. O wá ń fi gbogbo ọjọ́ ayé bẹ̀rù ibinu àwọn aninilára, nítorí wọ́n múra tán láti pa ọ́ run? Ibinu àwọn aninilára kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́.


Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu, mo ti pa ọ́ mọ́ lábẹ́ òjìji ọwọ́ mi. Èmi ni mo fi ojú ọ̀run sí ipò rẹ̀, tí mo fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí mo sì sọ fún ìlú Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni eniyan mi.’ ”


OLUWA ní, “Mo dá ọ̀run tuntun, ati ayé tuntun; a kò ní ranti àwọn ohun àtijọ́ mọ́, tabi kí wọn sọ sí eniyan lọ́kàn.


Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé, tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀, tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ.


‘OLUWA, Ọlọrun! Ìwọ tí o dá ọ̀run ati ayé pẹlu agbára ńlá ati ipá rẹ! Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ,


OLUWA ni ó fi agbára rẹ̀ dá ilé ayé, tí ó fi ìdí ayé múlẹ̀ pẹlu ìmọ̀ rẹ̀, ó sì fi òye rẹ̀ ta àwọn ọ̀run bí aṣọ.


Iṣẹ́ tí OLUWA rán sí Israẹli nìyí, OLUWA tí ó ta ọ̀run bí aṣọ, tí ó dá ayé, tí ó sì dá ẹ̀mí sinu eniyan, ni ó sọ báyìí pé,


Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè.


Nítorí ìpọ́njú yóo wà ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ohun gbogbo títí di àkókò yìí, kò sì ní sí irú rẹ̀ mọ́ lae.


“Ẹ̀yin eniyan, kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe irú eléyìí? Eniyan bíi yín ni àwa náà. À ń waasu fun yín pé kí ẹ yipada kúrò ninu àwọn ohun asán wọnyi, kí ẹ sin Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, ati òkun ati ohun gbogbo tí ó wà ninu wọn.


Ọlọrun tí ó dá ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, Oluwa ọ̀run ati ayé, kì í gbé ilé oriṣa àfọwọ́kọ́;


Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n jọ ké pe Ọlọrun pé, “Oluwa, ìwọ tí ó dá ọ̀run ati ayé ati òkun ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn,


Nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ohun gbogbo wà, láti ọwọ́ rẹ̀ ni ohun gbogbo ti ń wá, nítorí tirẹ̀ sì ni ohun gbogbo ṣe wà. Tirẹ̀ ni ògo títí ayérayé. Amin.


ṣugbọn ní tiwa, Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba, lọ́dọ̀ ẹni tí gbogbo nǹkan ti wá, ati lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ń lọ. Oluwa kan ni ó wà. Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí a dá gbogbo nǹkan, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá àwa náà.


Ati pé kí n ṣe àlàyé nípa ètò àṣírí yìí, tí Ọlọrun ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́,


Ó tún sọ pé, “O ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, Oluwa, ìwọ ni o fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀. Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni àwọn ọ̀run.


Ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó wá bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó fi ṣe àrólé ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá ayé.


Nípa igbagbọ ni ó fi yé wa pé ọ̀rọ̀ ni Ọlọrun fi dá ayé, tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a kò rí ni ó fi ṣẹ̀dá ohun tí a rí.


Nítorí kò sí ilé kan tí kò jẹ́ pé eniyan ni ó kọ́ ọ. Ṣugbọn Ọlọrun ni ó ṣe ohun gbogbo.


Nítorí wọ́n fi ojú fo èyí dá pé, láti ìgbà àtijọ́ ni àwọn ọ̀run ti wà, ati pé láti inú omi ni ilẹ̀ ti jáde nípa àṣẹ Ọlọrun.


Ohun tí ó ti wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, ohun tí a ti gbọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ ìyè, tí a ti fi ojú ara wa rí, tí a wò dáradára, tí a fi ọwọ́ wa dìmú, òun ni à ń sọ fun yín.


ó fi ẹni tí ó wà láàyè lae ati títí laelae búra, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá ayé ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀, tí ó dá òkun ati ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Ó ní kò sí ìjáfara mọ́.


Ó bá kígbe pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí àkókò ìdájọ́ rẹ̀ dé! Ẹ júbà ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, òkun ati gbogbo orísun omi.”


Ó ní, “Ó parí! Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin. N óo fún ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ ní omi mu láti inú kànga omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.


Èmi ni Alfa ati Omega, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.”


“Kọ ìwé yìí sí angẹli ìjọ Laodikia pé: “Ẹni tí ń jẹ́ Amin, olóòótọ́ ati ẹlẹ́rìí òdodo, alákòóso ẹ̀dá Ọlọrun ní


“Oluwa Ọlọrun wa, ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ògo, ati ọlá ati agbára. Nítorí ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, ati pé nípa ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, nípa rẹ ni a sì ṣe dá wọn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan