Filipi 4:3 - Yoruba Bible3 Bẹ́ẹ̀ ni mo bẹ ìwọ náà, ẹlẹgbẹ́ mi tòótọ́, ran àwọn obinrin wọnyi lọ́wọ́, nítorí wọ́n ti bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ninu iṣẹ́ ìtànkálẹ̀ ìyìn rere pẹlu Kilẹmẹnti ati gbogbo olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù, àwọn tí orúkọ wọn wà ninu ìwé ìyè. Faic an caibideilBibeli Mimọ3 Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alajọru-ajaga mi tõtọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori nwọn mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti mbẹ ninu iwe ìye. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 Mo sì bẹ̀ yin pẹ̀lú bí alájọru àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìhìnrere, àti Klementi pẹ̀lú, àti àwọn olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè. Faic an caibideil |
Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè.