Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 3:2 - Yoruba Bible

2 Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ajá. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn oníṣẹ́ burúkú. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ọ̀kọlà!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ẹ kiyesara lọdọ awọn ajá, ẹ kiyesara lọdọ awọn oniṣẹ-buburu, ẹ kiyesara lọdọ awọn onilà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 3:2
31 Iomraidhean Croise  

Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin aṣebi, kí n lè pa òfin Ọlọrun mi mọ́.


Àwọn eniyan burúkú yí mi ká bí ajá; àwọn aṣebi dòòyì ká mi; wọ́n fa ọwọ́ ati ẹsẹ̀ mi ya.


Gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ idà, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ajá!


Bí ajá tíí pada sídìí èébì rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni òmùgọ̀ tó pada sí ìwà agọ̀ rẹ̀.


Ọpọlọpọ yóo kùnà ninu igbagbọ; wọn yóo tú àwọn mìíràn fó; wọn yóo sì kórìíra àwọn mìíràn.


“Ẹ ṣọ́ra fún àwọn wolii èké tí wọn máa ń wá sọ́dọ̀ yín. Ní òde, wọ́n dàbí aguntan, ṣugbọn ninu, ìkookò tí ó ya ẹhànnà ni wọ́n.


“Ẹ má ṣe fi nǹkan mímọ́ fún ajá, ẹ má sì ṣe fi ìlẹ̀kẹ̀ iyebíye yín siwaju ẹlẹ́dẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn yóo sì pada bù yín jẹ!


Kì í ṣe nǹkan ti òde ara ni eniyan fi ń jẹ́ Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìkọlà kì í ṣe kí á fabẹ gé ara.


Aposteli èké ni irú àwọn bẹ́ẹ̀. Ẹlẹ́tàn ni wọ́n, tí wọn ń farahàn bí aposteli Kristi.


Òmìnira ni a pè yín sí, ẹ̀yin ará, ṣugbọn kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín fún ìtẹ́lọ́rùn ara yín, ìfẹ́ ni kí ẹ máa fi ran ara yín lọ́wọ́.


Ṣugbọn bí ẹ bá ń bá ara yín jà, tí ẹ̀ ń bu ara yín ṣán, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa ara yín run.


Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.


Ìparun ni ìgbẹ̀yìn wọn. Ikùn wọn ni ọlọrun wọn. Ohun ìtìjú ni wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga. Afẹ́-ayé ni wọ́n gbé lékàn.


Nítorí àwa gan-an ni ọ̀kọlà, àwa tí à ń sin Ọlọrun nípa Ẹ̀mí, tí à ń ṣògo ninu Kristi Jesu, tí a kò gbára lé nǹkan ti ara,


Kí o fi igbagbọ ati ẹ̀rí-ọkàn rere jà. Àwọn nǹkan wọnyi ni àwọn mìíràn kọ̀, tí ọkọ̀ ìgbé-ayé igbagbọ wọn fi rì.


Wọ́n ń fi ẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n ń sẹ́ ẹ ninu ìwà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin ati aláìgbọràn, wọn kò yẹ fún iṣẹ́ rere kan.


Àwọn ni òtítọ́ òwe yìí ṣẹ mọ́ lára pé, “Ajá tún pada lọ kó èébì rẹ̀ jẹ.” Ati òwe kan tí wọn máa ń pa pé, “Ẹlẹ́dẹ̀ tí wọ́n fọ̀ nù yóo tún pada lọ yíràá ninu ẹrọ̀fọ̀.”


Nítorí àwọn kan ti yọ́ wọ inú ìjọ, àwọn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ nípa wọn lọ́jọ́ tó ti pẹ́ pé ìdájọ́ ń bọ̀ sórí wọn. Wọ́n jẹ́ aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, wọ́n yí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa pada sí àìdára láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú wọn, wọ́n sẹ́ Ọ̀gá wa kanṣoṣo ati Oluwa wa Jesu Kristi.


Mo mọ̀ pé o ní ìṣòro; ati pé o ṣe aláìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni ọ́ ní ọ̀nà mìíràn. Mo mọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní Juu ń sọ, àwọn tí kì í sì í ṣe Juu; tí ó jẹ́ pé ilé ìpàdé Satani ni wọ́n.


Ṣugbọn àwọn ojo, àwọn alaigbagbọ, àwọn ẹlẹ́gbin, àwọn apànìyàn, àwọn àgbèrè, àwọn oṣó, àwọn abọ̀rìṣà, ati gbogbo àwọn èké ni yóo ní ìpín wọn ninu adágún iná tí ń jó, tí a fi imí-ọjọ́ dá. Èyí ni ikú keji.”


Lóde ni àwọn ajá yóo wà ati àwọn oṣó ati àwọn àgbèrè, ati àwọn apànìyàn ati àwọn abọ̀rìṣà ati àwọn tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe èké.


N óo fi àwọn kan láti inú ilé ìpàdé Satani lé ọ lọ́wọ́, àwọn òpùrọ́ tí wọn ń pe ara wọn ní Juu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe Juu. N óo ṣe é tí wọn yóo fi wá sọ́dọ̀ rẹ, wọn yóo foríbalẹ̀ fún ọ, wọn yóo sì mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan