Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 3:1 - Yoruba Bible

1 Ní gbolohun kan, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa. Kò ṣòro fún mi láti kọ àwọn nǹkankan náà si yín, ó tilẹ̀ dára bẹ́ẹ̀ fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 LI akotan, ará, ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa. Kì iṣe inira fun mi lati kọwe ohun kanna si nyin, ṣugbọn fun nyin o jẹ ailewu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ ohun ààbò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 3:1
46 Iomraidhean Croise  

Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli ṣe gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ìró orin ayọ̀, tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí ohun èlò orin bíi ipè, fèrè, aro, hapu ati dùùrù kọ.


Ẹ máa fi orúkọ rẹ̀ ṣògo, kí ọkàn àwọn tí wọn ń sin OLUWA kún fún ayọ̀.


Wọ́n jẹ, wọ́n sì mu níwájú Ọlọrun ní ọjọ́ náà pẹlu ayọ̀ ńlá. Wọ́n tún fi Solomoni, ọmọ Dafidi, jẹ ọba lẹẹkeji. Wọ́n fi òróró yàn án ní ọba ní orúkọ OLUWA, Sadoku sì ni alufaa.


Nehemaya bá sọ fún wọn pé, “Ẹ máa lọ, ẹ jẹ ẹran ọlọ́ràá, ẹ mu waini dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ranṣẹ sí àwọn tí wọn kò bá ní, nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni ọjọ́ òní jẹ́ fún OLUWA wa, ẹ má sì banújẹ́, nítorí pé ayọ̀ OLUWA ni agbára yín.”


nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare, o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun.


Kí Israẹli máa yọ̀ ninu Ẹlẹ́dàá rẹ̀, kí àwọn ọmọ Sioni máa fò fún ayọ̀ pé àwọn ní Ọba.


Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA; ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́.


Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo! Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́.


Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́.


Àwọn nǹkan wọnyi ni mò ń ranti, bí mo ti ń tú ẹ̀dùn ọkàn mi jáde: bí mo ṣe máa ń bá ogunlọ́gọ̀ eniyan rìn, tí mò ń ṣáájú wọn, bí a bá ti ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ sí ilé Ọlọrun; pẹlu ìhó ayọ̀ ati orin ọpẹ́, láàrin ogunlọ́gọ̀ eniyan tí ń ṣe àjọ̀dún.


Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn, kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae. Dáàbò bò wọ́n, kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ.


OLUWA jọba, kí ayé ó yọ̀; jẹ́ kí inú ogunlọ́gọ̀ erékùṣù ó dùn.


Ẹ óo fẹ́ wọn bí ọkà, atẹ́gùn yóo gbé wọn lọ, ìjì yóo sì fọ́n wọn ká. Ẹ̀yin óo yọ̀ ninu OLUWA ẹ óo sì ṣògo ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli.


N óo máa yọ̀ ninu OLUWA, ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi. Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù, ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ; bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.


Àwọn iranṣẹ mi yóo máa kọrin nítorí inú wọn dùn, ṣugbọn ẹ̀yin óo máa kígbe oró àtọkànwá; ẹ óo sì máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí àròkàn.


“Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni, kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín; nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò, ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín: ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.


Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó; ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!


OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín, akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni; yóo láyọ̀ nítorí yín, yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín, yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè


Nígbà tó bá yá, ilé Efuraimu yóo dàbí jagunjagun alágbára, inú wọn yóo sì dùn bí inú ẹni tí ó mu ọtí waini. Nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá rí i, inú wọn yóo dùn, ọkàn wọn yóo sì yin OLUWA.


Ẹ máa yọ̀, kí inú yín máa dùn, nítorí èrè yín pọ̀ ní ọ̀run. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wolii tí ó ti wà ṣiwaju yín.


ẹ̀mí mi yọ̀ sí Ọlọrun, Olùgbàlà mi,


Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣugbọn à ń yọ̀ ninu Ọlọrun nítorí ohun tí ó ṣe nípa Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí ó sọ wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun ní àkókò yìí.


Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ó dìgbà! Ẹ tún ọ̀nà yín ṣe. Ẹ gba ìkìlọ̀ wa. Ẹ ní ọkàn kan náà láàrin ara yín. Ẹ máa gbé pọ̀ ní alaafia. Ọlọrun ìfẹ́ ati alaafia yóo wà pẹlu yín.


Ní ìparí, ẹ jẹ́ alágbára ninu Oluwa, kí ẹ fi agbára rẹ̀ ṣe okun yín.


Níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn, ni kí ẹ ti jẹ ẹ́; ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín, lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wà ninu ìlú yín. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.


Ẹ óo máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé àwọn ìlú yín; àwọn àlejò, àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà láàrin yín.


Nítorí àwa gan-an ni ọ̀kọlà, àwa tí à ń sin Ọlọrun nípa Ẹ̀mí, tí à ń ṣògo ninu Kristi Jesu, tí a kò gbára lé nǹkan ti ara,


Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo. Mo tún wí: ẹ máa yọ̀.


Ní ìparí, ẹ̀yin ará, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe òtítọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá lọ́lá, gbogbo nǹkan tí ó bá tọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ́ mímọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá fa eniyan mọ́ra, gbogbo nǹkan tí ó bá ní ìròyìn rere, àwọn ni kí ẹ máa kó lé ọkàn.


Ẹ̀yin ará, ní ìparí ọ̀rọ̀ mi, a fi Jesu Oluwa bẹ̀ yín, a sì rọ̀ yín pé gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ wa ní ọ̀nà tí ó yẹ, kí ẹ máa rìn bí ó ti wu Ọlọrun. Bí ẹ ti ń ṣe ni kí ẹ túbọ̀ máa ṣe.


Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo.


Ẹ̀yin ará mi, ẹ kà á sí ayọ̀ gidi nígbà tí oríṣìíríṣìí ìdánwò bá dé ba yín.


Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀.


Èyí sọ yín di alábàápín ninu ìjìyà Kristi. Ẹ máa yọ̀. Nígbà tí ó bá pada dé ninu ògo rẹ̀, ayọ̀ ńlá ni ẹ óo yọ̀.


Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, èyí ni ìwé keji tí mo kọ si yín. Ninu ìwé mejeeji, mò ń ji yín pẹ́pẹ́, láti ran yín létí àwọn ohun tí ẹ mọ̀, kí ẹ lè fi ọkàn tòótọ́ rò wọ́n jinlẹ̀.


Hana bá gbadura báyìí pé: “Ọkàn mi kún fún ayọ̀ ninu OLUWA, Ó sọ mí di alágbára; mò ń fi àwọn ọ̀tá mi rẹ́rìn-ín, nítorí mò ń yọ̀ pé OLUWA gbà mí là.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan