Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 2:4 - Yoruba Bible

4 Ẹ má máa mójútó nǹkan ti ara yín nìkan, ṣugbọn ẹ máa mójútó nǹkan àwọn ẹlòmíràn náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ki olukuluku nyin ki o máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 2:4
15 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Modekai gbọ́ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ fún Ẹsita, ayaba, Ẹsita bá tètè lọ sọ fún ọba pé Modekai ni ó gbọ́ nípa ète náà tí ó sọ fún òun.


Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ jókòó níhìn-ín kí àwọn arakunrin yín máa lọ jagun ni?


“Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á sọ ọ́ sinu ibú òkun.


Àwọn tí ń yọ̀, ẹ bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sunkún, ẹ bá wọn sunkún.


Ó yẹ kí àwa tí a jẹ́ alágbára ninu igbagbọ máa fara da àwọn nǹkan tí àwọn tí igbagbọ wọn kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ bá ń ṣiyèméjì lé lórí. A kò gbọdọ̀ máa tẹ́ ara wa nìkan lọ́rùn.


Kí ẹnikẹ́ni má ṣe máa wá ire ti ara rẹ̀ bíkòṣe ire ẹnìkejì rẹ̀.


Ta ni jẹ́ aláìlera tí n kò ní ìpín ninu àìlera rẹ̀? Ta ni ṣubú sinu ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkàn mi kò bàjẹ́?


A kò fi ohun ìkọsẹ̀ kankan siwaju ẹnikẹ́ni, kí àwọn eniyan má baà rí wí sí iṣẹ́ wa.


Nítorí nǹkan ti ara wọn ni gbogbo àwọn yòókù ń wá, wọn kò wá nǹkan ti Jesu Kristi.


Ẹ̀ ń ṣe dáradára tí ẹ bá pa òfin ìjọba Ọlọrun mọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé, “Ìwọ fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan