Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 2:3 - Yoruba Bible

3 Ẹ má ṣe ohunkohun pẹlu ẹ̀mí àṣehàn tabi láti gba ìyìn eniyan, ṣugbọn pẹlu ọkàn ìrẹ̀lẹ̀, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣiwaju ara yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa ara tàbí ògo asán, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 2:3
24 Iomraidhean Croise  

Ìjà ni ìgbéraga máa ń fà, ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá gba ìmọ̀ràn yóo ní ọgbọ́n.


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé agbowó-odè yìí lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ọkàn ìdáláre ju èyí Farisi lọ. Nítorí ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”


Ẹ ní ìfẹ́ láàrin ara yín bíi mọ̀lẹ́bí. Ní ti bíbu ọlá fún ara yín, ẹ máa fi ti ẹnìkejì yín ṣiwaju.


Ẹ jẹ́ kí á máa rìn bí ó ti yẹ ní ọ̀sán, kí á má wà ninu àwùjọ aláriwo ati ọ̀mùtí, kí á má máa ṣe ìṣekúṣe, kí á má máa hu ìwà wọ̀bìà, kí á má máa ṣe aáwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí á má máa jowú.


Ṣugbọn ní ti àwọn tí ó jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ati àwọn tí kò gba òtítọ́, àwọn tí wọ́n gba ohun burúkú, Ọlọrun yóo fi ibinu ati ìrúnú rẹ̀ hàn wọ́n;


Nítorí èmi ni mo kéré jùlọ ninu àwọn aposteli. N kò tilẹ̀ yẹ ní ẹni tí wọn ìbá máa pè ní aposteli, nítorí pé mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọrun.


nítorí bí ẹlẹ́ran-ara ni ẹ̀ ń hùwà sibẹ. Nítorí níwọ̀n ìgbà tí owú jíjẹ ati ìjà bá wà láàrin yín, ṣé kò wá fihàn pé bí ẹlẹ́ran-ara ati eniyan kan lásán ni ẹ̀ ń hùwà.


Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà ti mo bá dé, mo lè má ba yín ní irú ipò tí mo fẹ́, ati pé ẹ̀yin náà lè rí i pé n kò rí bí ẹ ti ń rò. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ohun tí n óo bá láàrin yín má jẹ́ ìjà ati owú jíjẹ, ibinu ati ìwà ọ̀kánjúwà, ọ̀rọ̀ burúkú ati ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga ati ìrúkèrúdò.


Ṣugbọn bí ẹ bá ń bá ara yín jà, tí ẹ̀ ń bu ara yín ṣán, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa ara yín run.


Ẹ má jẹ́ kí á máa ṣe ògo asán, kí á má máa rú ìjà sókè láàrin ara wa, kí á má sì máa jowú ara wa.


Kí ẹ máa hùwà pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ọkàn tútù, kí ẹ sì máa mú sùúrù. Kí ẹ máa fi ìfẹ́ bá ara yín lò nípa ìfaradà.


Ẹ máa tẹríba fún ara yín nítorí ọ̀wọ̀ tí ẹ̀ ń bù fún Kristi.


Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú tabi iyàn jíjà,


Nítorí náà, ẹ gbé àánú wọ̀ bí ẹ̀wù, ati inú rere, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ ati sùúrù, bí ó ti yẹ àwọn ẹni tí Ọlọrun yàn, tí wọ́n sì jẹ́ eniyan Ọlọrun ati àyànfẹ́ rẹ̀.


Ṣugbọn ní àkókò yìí, ẹ pa gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tì: ibinu, inúfùfù, ìwà burúkú, ìsọkúsọ, ọ̀rọ̀ ìtìjú.


ìgbéraga ti sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di aṣiwèrè, kò sì mọ nǹkankan. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ óo fẹ́ràn láti máa ṣe òfintótó ọ̀ràn, ati iyàn jíjà, àwọn ohun tí ó ń mú owú-jíjẹ, ìjà, ìsọkúsọ, ìfura burúkú,


Ní gbolohun kan, ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ ni ojú àánú. Ẹ ní ìfẹ́ sí ara yín. Ẹ máa ṣoore. Ẹ ní ọkàn ìrẹ̀lẹ̀.


Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan