Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 2:2 - Yoruba Bible

2 ẹ mú kí ayọ̀ mi kún nípa pé kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí ẹ fẹ́ nǹkankan náà, kí ẹ ní inú kan, kí èrò yín sì papọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ẹ mu ayọ̀ mi kún, ki ẹnyin ki o le jẹ oninu kanna, ki imọ̀ nyin ki o ṣọkan, ki ẹ si ni ọkàn kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 2:2
28 Iomraidhean Croise  

Nítorí ti àwọn ará ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi, n óo wí pé, “Kí alaafia ó wà ninu rẹ.”


Ọkọ iyawo ni ó ni iyawo, ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo, tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, á máa láyọ̀ láti gbọ́ ohùn ọkọ iyawo. Nítorí náà ayọ̀ mi yìí di ayọ̀ kíkún.


Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu.


Ní ọjọ́ Pẹntikọsti, gbogbo wọn wà pọ̀ ní ibìkan náà.


Wọ́n ń fi ọkàn kan lọ sí Tẹmpili lojoojumọ. Wọ́n jọ ń jẹun láti ilé dé ilé. Wọ́n jọ ń jẹun pẹlu ayọ̀ ati pẹlu ọkàn kan.


Ọpọlọpọ iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ni àwọn aposteli ṣe láàrin àwọn eniyan. Gbogbo wọn wà ní ìṣọ̀kan ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní ti Solomoni.


Ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ má ṣe gbèrò ohun gíga-gíga, ṣugbọn ẹ máa darapọ̀ mọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín.


Ẹ̀yin ará, mo fi orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi bẹ̀ yín, gbogbo yín, ẹ fohùn ṣọ̀kan, kí ó má sí ìyapa láàrin yín. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí èrò yín sì papọ̀.


Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ó dìgbà! Ẹ tún ọ̀nà yín ṣe. Ẹ gba ìkìlọ̀ wa. Ẹ ní ọkàn kan náà láàrin ara yín. Ẹ máa gbé pọ̀ ní alaafia. Ọlọrun ìfẹ́ ati alaafia yóo wà pẹlu yín.


Ìdí tí mo fi kọ ìwé tí mo kọ si yín nìyí, nítorí n kò fẹ́ wá kí n tún ní ìbànújẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yin tí ó yẹ kí ẹ fún mi láyọ̀. Ó dá mi lójú pé bí mo bá ń yọ̀, inú gbogbo yín ni yóo máa dùn.


Kì í sìí ṣe ti dídé tí ó dé nìkan ni, ṣugbọn ó ròyìn fún wa, gbogbo bí ẹ ti dá a lọ́kàn le ati gbogbo akitiyan yín lórí wa, bí ọkàn yín ti bàjẹ́ tó fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ati bí ẹ ti ní ìtara tó fún mi. Èyí mú kí inú mi dùn pupọ.


Nígbà gbogbo ni mò ń gbadura fún gbogbo yín pẹlu ayọ̀ ninu ọkàn mi.


tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo.


N kò ní ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀ tí ọkàn wa rí bákan náà, tí ó sì tún ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe àwọn nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ tiyín.


Mo bẹ Yuodia ati Sintike pé kí wọ́n bá ara wọn rẹ́ nítorí ti Oluwa.


Nítorí bí n kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa ti ara, sibẹ mo wà pẹlu yín ninu ẹ̀mí. Mo láyọ̀ nígbà tí mo rí ètò tí ó wà láàrin yín ati bí igbagbọ yín ti dúró ninu Kristi.


Ṣugbọn ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Oluwa, nítorí Ọlọrun ti yàn yín láti ìbẹ̀rẹ̀ wá láti gbà yín là nípa Ẹ̀mí tí ó sọ yín di mímọ́, ati nípa gbígba òtítọ́ gbọ́.


Nígbà tí mo bá ranti ẹkún tí o sun, a dàbí kí n tún rí ọ, kí ayọ̀ mi lè di kíkún.


Arakunrin mi, mo fẹ́ kí o yọ̀ǹda ọ̀rọ̀ yìí fún mi nítorí Oluwa. Fi ọkàn mi balẹ̀ ninu Kristi.


Mo láyọ̀ pupọ nítorí mo ti rí àwọn tí wọn ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́ ninu àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí a ti gba òfin lọ́dọ̀ Baba.


Ayọ̀ mi kì í lópin, nígbà tí mo bá gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan