Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 1:9 - Yoruba Bible

9 Adura mi ni pé kí ìfẹ́ yín máa gbòòrò sí i, kí ìmọ̀ yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ túbọ̀ máa ní làákàyè sí i,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Eyi si ni mo ngbadura fun pe, ki ifẹ nyin ki o le mã pọ si i siwaju ati siwaju ninu imọ̀ ati imoye gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 1:9
19 Iomraidhean Croise  

Kí Oluwa mú kí ìfẹ́ yín sí ara yín ati sí gbogbo eniyan kí ó pọ̀ sí i, kí ó sì túbọ̀ jinlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí tiwa ti rí si yín.


Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí.


Adura mi ni pé kí àjọṣepọ̀ tàwa-tìrẹ ninu igbagbọ lè ṣiṣẹ́, láti mú kí òye rẹ pọ̀ sí i nípa gbogbo ohun rere tí a ní ninu Kristi.


tí ẹ ti gbé ẹ̀dá titun wọ̀. Èyí ni ẹ̀dá tí ó túbọ̀ ń di titun siwaju ati siwaju gẹ́gẹ́ bí àwòrán ẹni tí ó dá a, tí ó ń mú kí eniyan ní ìmọ̀ Ọlọrun.


Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn sí àwọn onigbagbọ ara yín, ẹ fi tinútinú fẹ́ràn ọmọnikeji yín.


Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ní, tí ẹ sì ní lọpọlọpọ: igbagbọ, ọ̀rọ̀ sísọ, ìmọ̀, ati ìtara ní ọ̀nà gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí ẹ ní sí wa. A fẹ́ kí ìtara yín túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìfẹ́ pẹlu.


Ará, ẹ má máa ṣe bí ọmọde ninu èrò yín. Ó yẹ kí ẹ dàbí ọmọde tí kò mọ ibi, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ àgbàlagbà ninu èrò yín.


Ẹ̀yin ará, ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí yín. Ó tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé igbagbọ yín ń tóbi sí i, ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sí ara yín sì ń pọ̀ sí i.


Ṣugbọn ẹ máa dàgbà ninu oore-ọ̀fẹ́ ati ìmọ̀ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi. Tirẹ̀ ni ògo nisinsinyii ati títí laelae. Amin.


Ṣugbọn oúnjẹ gidi ni àgbàlagbà máa ń jẹ, àwọn tí ìrírí wọn fún ọjọ́ pípẹ́ ti fún ní òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan rere ati nǹkan burúkú.


Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ aṣiwèrè, ṣugbọn kí ẹ máa fi òye gbé ohun tíí ṣe ìfẹ́ Oluwa.


Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́, tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere.


Ẹ̀yin ará, ní ìparí ọ̀rọ̀ mi, a fi Jesu Oluwa bẹ̀ yín, a sì rọ̀ yín pé gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ wa ní ọ̀nà tí ó yẹ, kí ẹ máa rìn bí ó ti wu Ọlọrun. Bí ẹ ti ń ṣe ni kí ẹ túbọ̀ máa ṣe.


Sibẹsibẹ olódodo kò fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́ sì ń lágbára sí i.


Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé, nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan