Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filipi 1:10 - Yoruba Bible

10 kí ẹ lè mọ àwọn ohun tí ó dára jùlọ. Kí ẹ lè jẹ́ aláìlábùkù, kí ẹ sì wà láìsí ohun ìkùnà kan ní ọjọ́ tí Kristi bá dé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ki ẹnyin ki o le dán ohun ti o yàtọ wò; ki ẹ si jasi olododo ati alaijẹ-ohun-ikọsẹ titi fi di ọjọ Jesu Kristi;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filipi 1:10
43 Iomraidhean Croise  

Ṣebí ẹnu ara rẹ̀ ni ó fi sọ pé arabinrin òun ni, tí obinrin náà sì sọ pé arakunrin òun ni. Ohun tí mo ṣe tí ó di ẹ̀ṣẹ̀ yìí, òtítọ́ inú ati àìmọ̀ ni mo fi ṣe é.”


Ṣebí etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, ahọ́n a sì máa tọ́ oúnjẹ wò?


nítorí bí ahọ́n ti í máa ń tọ́ oúnjẹ wò, bẹ́ẹ̀ ni etí náà lè máa tọ́ ọ̀rọ̀ wò


Ẹ̀yin tí ẹ kórìíra ohun rere, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi, ẹ̀yin tí ẹ bó awọ lára àwọn eniyan mi, tí ẹ sì ya ẹran ara egungun wọn;


Ṣugbọn Jesu yipada, ó sọ fún Peteru pé, “Kó ara rẹ̀ kúrò níwájú mi, Satani. Ohun ìkọsẹ̀ ni o jẹ́ fún mi, nítorí o kò ro nǹkan ti Ọlọrun, ti eniyan ni ò ń rò.”


Peteru dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo àwọn yòókù bá tilẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ, bíi tèmi kọ́!”


Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.”


Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe burúkú a máa kórìíra ìmọ́lẹ̀; kò jẹ́ wá sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ bá wà, kí eniyan má baà bá a wí nítorí iṣẹ́ rẹ̀.


Ìdí nìyí tí mo fi ń sa ipá mi kí ọkàn mi lè jẹ́ mi lẹ́rìí pé inú mi mọ́ sí Ọlọrun ati eniyan nígbà gbogbo.


Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ para dà, kí ọkàn yín di titun, kí ẹ lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé.


Ìfẹ́ yín kò gbọdọ̀ ní ẹ̀tàn ninu. Ẹ kórìíra nǹkan burúkú. Ẹ fara mọ́ àwọn nǹkan rere.


Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín pé kí ẹ máa fura sí àwọn tí ó ń dá ìyapa sílẹ̀ ati àwọn tí ń múni ṣìnà, tí wọn ń ṣe àwọn nǹkan tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, ẹ yẹra fún irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀.


O mọ ohun tí Ọlọrun fẹ́. O mọ àwọn ohun tí ó dára jù nítorí a ti fi Òfin kọ́ ọ.


Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń ṣe àwọn nǹkan tí n kò fẹ́, mò ń jẹ́rìí sí i pé Òfin jẹ́ ohun tí ó dára.


Mo yọ̀ gidigidi ninu ọkàn mi pé Ọlọrun ṣe òfin.


Ìdí nìyí tí àwọn tí ń lépa nǹkan ti ẹran-ara nìkan fi jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun, nítorí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè fara wọn sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun; wọn kò tilẹ̀ lè ṣe é rárá ni.


ẹni tí yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ títí dé òpin, tí ẹ óo fi wà láì lẹ́gàn ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa, Jesu Kristi.


Ẹ má ṣe jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún àwọn Juu tabi fún àwọn tí kì í ṣe Juu tabi fún ìjọ Ọlọrun.


Nítorí náà, bí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni yóo bá gbé arakunrin mi ṣubú, n kò ní jẹ ẹran mọ́ laelae, kí n má baà ṣe ohun tí yóo gbé arakunrin mi ṣubú.


Nǹkankan wà tí a lè fi ṣe ìgbéraga, ẹ̀rí-ọkàn wa sì jẹ́rìí sí i pé pẹlu ọkàn kan ati inú kan níwájú Ọlọrun ni a fi ń bá gbogbo eniyan lò, pàápàá jùlọ ẹ̀yin gan-an. Kì í ṣe ọgbọ́n eniyan bíkòṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.


Nítorí àwa kì í ṣe àwọn tí ń ba ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ nítorí èrè tí wọn óo rí jẹ níbẹ̀, bí ọpọlọpọ tí ń ṣe. Ṣugbọn à ń waasu pẹlu ọkàn kan bí eniyan Kristi, ati gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọrun rán níṣẹ́, tí ó ń ṣiṣẹ́ níwájú Ọlọrun.


A kò fi ohun ìkọsẹ̀ kankan siwaju ẹnikẹ́ni, kí àwọn eniyan má baà rí wí sí iṣẹ́ wa.


N kò pa èyí láṣẹ. Mo fi àpẹẹrẹ ìtara àwọn ẹlòmíràn siwaju yín láti fi dán yín wò ni, bóyá ẹ ní ìfẹ́ tòótọ́ tabi ẹ kò ní.


Ará, tí ó bá jẹ́ pé iwaasu pé kí eniyan kọlà ni mò ń wà, kí ló dé tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ǹjẹ́ a ti mú ohun ìkọsẹ̀ agbelebu Kristi kúrò?


Ṣugbọn a óo máa sọ òtítọ́ pẹlu ìfẹ́, a óo máa dàgbà ninu rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà, ninu Kristi tíí ṣe orí.


Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa.


Kí ó lè mú ìjọ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó lọ́lá, tí kò ní àléébù kankan, tabi kí ó hunjọ, tabi kí ó ní nǹkan àbùkù kankan, ṣugbọn kí ó lè jẹ́ ìjọ mímọ́ tí kò ní èérí.


Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn Oluwa wa, Jesu Kristi pẹlu ìfẹ́ tí kò lópin.


Àwọn kan ń fi ìfẹ́ waasu Kristi nítorí wọ́n mọ̀ pé nítorí ti ọ̀rọ̀ ìyìn rere ni wọ́n ṣe sọ mí sẹ́wọ̀n.


Ó dá mi lójú pé ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere ninu yín yóo ṣe é dé òpin títí di ọjọ́ tí Kristi Jesu yóo dé.


tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo.


Kí Oluwa fi agbára fun yín, kí ọkàn yín lè wà ní ipò mímọ́, láìní àléébù, níwájú Ọlọrun Baba wa nígbà tí Oluwa wa Jesu bá farahàn pẹlu gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.


Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin.


Kí Ọlọrun alaafia kí ó yà yín sí mímọ́ patapata; kí ó pa gbogbo ẹ̀mí yín mọ́ ati ọkàn, ati ara yín. Kí èyíkéyìí má ní àbùkù nígbà tí Oluwa wa Jesu Kristi bá farahàn.


“Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú. Ẹ kó gbogbo oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò ati ní Ijipti dànù, kí ẹ sì máa sin OLUWA.


Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹni tí ó bá wí pé òun ní Ẹ̀mí Ọlọrun gbọ́. Ẹ kọ́kọ́ wádìí wọn láti mọ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nítorí ọpọlọpọ àwọn èké wolii ti wọ inú ayé.


Mo mọ iṣẹ́ rẹ, ati làálàá rẹ, ati ìfaradà rẹ. Mo mọ̀ pé o kò jẹ́ gba àwọn eniyan burúkú mọ́ra. O ti dán àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọn kì í ṣe aposteli wò, o ti rí i pé òpùrọ́ ni wọ́n.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan