Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:9 - Yoruba Bible

9 ṣugbọn nítorí ìfẹ́ tí ó wà láàrin wa, ẹ̀bẹ̀ ni n óo kúkú bẹ̀. Èmi Paulu, ikọ̀ Kristi, tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nisinsinyii nítorí ti Kristi Jesu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Ṣugbọn nitori ifẹ emi kuku bẹ̀bẹ, iru ẹni bi emi Paulu arugbo, ati nisisiyi ondè Kristi Jesu pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:9
17 Iomraidhean Croise  

Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi, Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀, títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ, àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀.


Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi; má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́.


Adé ògo ni ewú orí, nípa ìgbé ayé òdodo ni a fi lè ní i.


Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín, n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí. Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín, n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là.


Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ̀yin ará, mo fỌlọrun aláàánú bẹ̀ yín pé kí ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ bí ẹbọ mímọ́ tí ó yẹ láti fi sin Ọlọrun. Èyí ni iṣẹ́ ìsìn tí ó yẹ yín.


Nítorí náà, a jẹ́ aṣojú fún Kristi. Ó dàbí ẹni pé àwa ni Ọlọrun ń lò láti fi bẹ̀ yín. A fi orúkọ Kristi bẹ̀ yín, ẹ bá Ọlọrun rẹ́.


Gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ má ṣe jẹ́ kí gbígbà tí ẹ gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jẹ́ lásán.


Nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ Ọlọrun nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu.


Ìdí rẹ̀ nìyí tí èmi Paulu fi di ẹlẹ́wọ̀n fún Kristi Jesu nítorí ti ẹ̀yin tí ẹ kì í ṣe Juu.


Nítorí náà, èmi tí mo di ẹlẹ́wọ̀n nítorí ti Oluwa, ń bẹ̀ yín pé kí ẹ máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, bí irú ìpè tí Ọlọrun pè yín.


tí mo jẹ́ ikọ̀ fún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mí. Ẹ gbadura pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ bí ó ti yẹ.


Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Kristi Jesu Oluwa wa, ẹni tí ń fún mi ní agbára. Mo dúpẹ́ nítorí ó kà mí yẹ láti fún mi ní iṣẹ́ rẹ̀,


Àwọn àgbà ọkunrin níláti jẹ́ ẹni tí ó ń ṣe pẹ̀lẹ́, ẹni ọ̀wọ̀, ọlọ́gbọ́n, tí ó jinná ninu igbagbọ, ninu ìfẹ́ ati ninu ìfaradà.


Nítorí náà mo tún bẹ̀ yín gidigidi pé kí ẹ máa gbadura fún wa, kí wọ́n baà lè dá mi sílẹ̀ kíákíá láti wá sọ́dọ̀ yín.


Ẹ̀yin olùfẹ́ tí ẹ jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì, mo bẹ̀ yín, ẹ jìnnà sí àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tí ó ń bá ọkàn jagun.


Nígbà tí àwọn baba wọn, tabi àwọn arakunrin wọn bá wá fi ẹjọ́ sùn wá, a óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún wọn nítorí pé àwọn obinrin tí a rí fún wọn ninu ogún kò kárí; kì í kúkú ṣe pé ẹ fi àwọn ọmọbinrin wọnyi fún wọn ni, tí ègún yóo fi ṣẹ le yín lórí.’ ”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan