Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:7 - Yoruba Bible

7 Nítorí mo láyọ̀ pupọ, mo sì ní ìwúrí lọpọlọpọ nípa ìfẹ́ rẹ. Nítorí ohun tí ò ń ṣe ti tu àwọn onigbagbọ lára, arakunrin mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Emi sá ni ayọ̀ pupọ ati itunu nitori ifẹ rẹ, nitoriti a tù ọkàn awọn enia mimọ́ lara lati ọwọ́ rẹ wá, arakunrin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:7
11 Iomraidhean Croise  

Wọ́n mú kí ọkàn mi balẹ̀. Ati ti ẹ̀yin náà. Ẹ máa yẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí.


Ìdí rẹ̀ nìyí tí a fi ní ìtùnú. Lẹ́yìn pé a ní ìtùnú, a tún ní ayọ̀ pupọ nígbà tí a rí bí ayọ̀ Titu ti pọ̀ tó, nítorí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láàrin gbogbo yín.


Ọkàn mi balẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yín. Mò ń fi ọwọ́ yín sọ̀yà. Mò ti ní ìtùnú kíkún. Ninu gbogbo ìpọ́njú wa, mo ní ayọ̀ lọpọlọpọ.


Ninu adura wa sí Ọlọrun Baba wa, à ń ranti bí igbagbọ yín ti ń mú kí ẹ ṣiṣẹ́, tí ìfẹ́ yín ń jẹ́ kí ẹ ṣe akitiyan, tí ìrètí tí ẹ ní ninu Oluwa wa Jesu Kristi sì ń mú kí ẹ ní ìfaradà.


Nítorí náà, àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ẹ gbọ́ lẹ́nu wa, ẹ gbà á bí ó ti rí gan-an ni. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ẹ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ eniyan. Ọ̀rọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ ninu ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́.


Nítorí tí kò bá ṣe ẹ̀yin, ta tún ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, ati adé tí a óo máa fi ṣògo níwájú Oluwa wa Jesu nígbà tí ó bá farahàn?


Nítorí pé ọpẹ́ mélòó ni a lè dá lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, lórí gbogbo ayọ̀ tí à ń yọ̀ nítorí yín níwájú Ọlọrun wa?


Kí Oluwa ṣàánú ìdílé Onesiforosi. Kò ní iye ìgbà tí ó ti tù mí ninu, ninu ìṣòro mi. Kò tijú pé ẹlẹ́wọ̀n ni mí.


Arakunrin mi, mo fẹ́ kí o yọ̀ǹda ọ̀rọ̀ yìí fún mi nítorí Oluwa. Fi ọkàn mi balẹ̀ ninu Kristi.


Mo láyọ̀ pupọ nítorí mo ti rí àwọn tí wọn ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́ ninu àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí a ti gba òfin lọ́dọ̀ Baba.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan