Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:6 - Yoruba Bible

6 Adura mi ni pé kí àjọṣepọ̀ tàwa-tìrẹ ninu igbagbọ lè ṣiṣẹ́, láti mú kí òye rẹ pọ̀ sí i nípa gbogbo ohun rere tí a ní ninu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ki idapọ igbagbọ́ rẹ le lagbara, ni imọ ohun rere gbogbo ti mbẹ ninu nyin si Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:6
18 Iomraidhean Croise  

Kíá, bí ó ti lọ tán, ẹni tí ó gba àpò marun-un lọ ṣòwò, ó bá jèrè àpò marun-un.


Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo.


Àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ ọkàn rẹ̀ yóo hàn kedere, ni yóo bá dojúbolẹ̀, yóo sì júbà Ọlọrun. Yóo sọ pé, “Dájúdájú Ọlọrun wà láàrin yín.”


Nítorí pé mo ní anfaani pupọ láti ṣiṣẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò pọ̀.


Ní ìparí, ẹ̀yin ará, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe òtítọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá lọ́lá, gbogbo nǹkan tí ó bá tọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ́ mímọ́, gbogbo nǹkan tí ó bá fa eniyan mọ́ra, gbogbo nǹkan tí ó bá ní ìròyìn rere, àwọn ni kí ẹ máa kó lé ọkàn.


Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí.


tí ẹ ti gbé ẹ̀dá titun wọ̀. Èyí ni ẹ̀dá tí ó túbọ̀ ń di titun siwaju ati siwaju gẹ́gẹ́ bí àwòrán ẹni tí ó dá a, tí ó ń mú kí eniyan ní ìmọ̀ Ọlọrun.


Àwọn eniyan wa níláti kọ́ láti ṣe iṣẹ́ rere kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà wọn; wọn kò gbọdọ̀ jókòó tẹtẹrẹ láìṣe nǹkankan.


Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii.


Ẹ̀yin ará mi, èrè kí ni ó jẹ́, tí ẹnìkan bá sọ pé òun ní igbagbọ, ṣugbọn tí igbagbọ yìí kò hàn ninu iṣẹ́ rẹ̀? Ṣé igbagbọ yìí lè gbà á là?


Bẹ́ẹ̀ gan-an ni igbagbọ tí kò bá ní iṣẹ́: òkú ni.


Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́.


Bákan náà ni kí ẹ̀yin aya máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín. Ìdí rẹ̀ ni pé bí a bá rí ninu àwọn ọkọ tí kò jẹ́ onigbagbọ, wọ́n lè yipada nípa ìwà ẹ̀yin aya wọn láìjẹ́ pé ẹ bá wọn sọ gbolohun kan nípa ẹ̀sìn igbagbọ,


Ṣugbọn kí ẹ dáhùn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní àìdára, ojú yóo ti àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa yín, nígbà tí wọn bá rí ìgbé-ayé yín gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.


Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan