Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:20 - Yoruba Bible

20 Arakunrin mi, mo fẹ́ kí o yọ̀ǹda ọ̀rọ̀ yìí fún mi nítorí Oluwa. Fi ọkàn mi balẹ̀ ninu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

20 Nitõtọ, arakunrin, jẹ ki emi ki o ni ayọ̀ rẹ ninu Oluwa: tù ọkan mi lara ninu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

20 Èmi ń fẹ́, arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:20
14 Iomraidhean Croise  

Wọ́n mú kí ọkàn mi balẹ̀. Ati ti ẹ̀yin náà. Ẹ máa yẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí.


Bí mo bá bà yín ninu jẹ́, ta ni yóo mú inú mi dùn bí kò bá ṣe ẹ̀yin kan náà tí mo bà ninu jẹ́?


Ìdí rẹ̀ nìyí tí a fi ní ìtùnú. Lẹ́yìn pé a ní ìtùnú, a tún ní ayọ̀ pupọ nígbà tí a rí bí ayọ̀ Titu ti pọ̀ tó, nítorí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láàrin gbogbo yín.


Mo fi Ọlọrun ṣe ẹ̀rí pé àárò gbogbo yín ń sọ mí, pẹlu ọkàn ìyọ́nú ti Kristi Jesu.


Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, àyànfẹ́, tí ọkàn mi ń fà sí, ayọ̀ mi, ati adé mi, ẹ dúró gbọningbọnin ninu Oluwa.


Òun ni mò ń rán pada sí ọ. Ó wá dàbí ẹni pé mò ń fi ọkàn èmi pàápàá ranṣẹ sí ọ.


Nítorí mo láyọ̀ pupọ, mo sì ní ìwúrí lọpọlọpọ nípa ìfẹ́ rẹ. Nítorí ohun tí ò ń ṣe ti tu àwọn onigbagbọ lára, arakunrin mi.


Kí ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn aṣiwaju yín lẹ́nu, kí ẹ máa tẹ̀lé ìlànà wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe akitiyan láìṣe àárẹ̀ láti tọ́jú yín, pẹlu ọkàn pé wọn yóo jíyìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọrun. Ẹ mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ayọ̀ fún wọn, ẹ má jẹ́ kí ó jẹ́ ìrora. Bí ẹ bá mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ìrora fún wọn, kò ní ṣe yín ní anfaani.


Bí ẹnìkan bá ní dúkìá ayé yìí, tí ó rí arakunrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí kò ṣàánú rẹ̀, a ṣe lè wí pé ìfẹ́ Ọlọrun ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀?


Ayọ̀ mi kì í lópin, nígbà tí mo bá gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan