Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:14 - Yoruba Bible

14 Ṣugbọn n kò fẹ́ dá nǹkankan ṣe láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ sí i, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé túlààsì ni oore tí mo fẹ́ kí o ṣe. Inú rẹ ni mo fẹ́ kí ó ti wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

14 Ṣugbọn li aimọ̀ inu rẹ emi kò fẹ ṣe ohun kan; ki ore rẹ ki o má ba dabi afiyanjuṣe, bikoṣe tifẹtifẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:14
10 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun mi, mo mọ̀ pé ò máa yẹ ọkàn wò, o sì ní inú dídùn sí òtítọ́; tọkàntọkàn mi ni mo fi mú gbogbo nǹkan wọnyi wá fún ọ, mo sì ti rí i bí àwọn eniyan rẹ ti fi tọkàntọkàn ati inú dídùn mú ọrẹ wọn wá fún ọ.


Àwọn eniyan rẹ yóo fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀, lọ́jọ́ tí o bá ń kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ lórí òkè mímọ́. Àwọn ọ̀dọ́ yóo jáde tọ̀ ọ́ wá bí ìrì òwúrọ̀.


Nítorí bí ó bá jẹ́ pé èmi fúnra mi ni mo yàn láti máa ṣe iṣẹ́ yìí, mo ní ẹ̀tọ́ láti retí èrè níbẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ dandan ni mo fi ń ṣe é, iṣẹ́ ìríjú tí a fi sí ìtọ́jú mi ni.


Ta ló jẹ́ ṣe iṣẹ́ ọmọ-ogun tí yóo tún máa bọ́ ara rẹ̀? Ta ló jẹ́ dá oko láì má jẹ ninu èso rẹ̀? Ta ló jẹ́ máa tọ́jú aguntan láìmu ninu wàrà aguntan tí ó ń tọ́jú?


Kì í ṣe pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fi agbára ti igbagbọ bọ̀ yín lọ́rùn ni, nítorí ẹ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu igbagbọ. Ṣugbọn a jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu yín ni, kí ẹ lè ní ayọ̀.


Bí ìfẹ́ láti mú ọrẹ wá bá wà, Ọlọrun gba ohun tí eniyan bá mú wá. Ọlọrun kò bèèrè ohun tí eniyan kò ní.


Nítorí náà, mo rí i pé ó di dandan pé kí n bẹ àwọn arakunrin láti ṣiwaju mi wá sọ́dọ̀ yín, kí wọ́n ṣe ètò sílẹ̀ nípa ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣe ìlérí, kí ó jẹ́ pé yóo ti wà nílẹ̀ kí n tó dé. Èyí yóo mú kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, kò ní jẹ́ ti ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà.


Kí olukuluku ṣe bí ó bá ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìkanra, tabi àfipáṣe, nítorí onínúdídùn ọlọ́rẹ ni Ọlọrun fẹ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan