Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:12 - Yoruba Bible

12 Òun ni mò ń rán pada sí ọ. Ó wá dàbí ẹni pé mò ń fi ọkàn èmi pàápàá ranṣẹ sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:12
10 Iomraidhean Croise  

Dafidi sọ fún Abiṣai ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣebí ọmọ tèmi gan-an ni ó ń gbìyànjú láti pa mí yìí, kí ló dé tí ọ̀rọ̀ ti ará Bẹnjamini yìí fi wá jọ yín lójú. OLUWA ni ó ní kí ó máa ṣépè, nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣẹ́ ẹ.


“Ṣé ọmọ mi ọ̀wọ́n ni Efuraimu ni? Ṣé ọmọ mi àtàtà ni? Nítorí bí mo tí ń sọ̀rọ̀ ibinu sí i tó, sibẹ mò ń ranti rẹ̀, nítorí náà ọkàn rẹ̀ ń fà mí; dájúdájú n óo ṣàánú rẹ̀.


Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [


Ó bá dìde, ó lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀. “Bí ó ti ń bọ̀ ní òkèèrè ni baba rẹ̀ ti rí i. Àánú ṣe é, ó yára, ó dì mọ́ ọn lọ́rùn, ó bá fẹnu kò ó ní ẹnu.


Ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú; kí ẹ sì máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti dáríjì yín nípasẹ̀ Kristi.


“Bí ẹnikẹ́ni bá ń tàn ọ́ níkọ̀kọ̀ pé kí o lọ bọ oriṣa-koriṣa kan, tí ìwọ tabi àwọn baba rẹ kò bọ rí, olúwarẹ̀ kì báà jẹ́ arakunrin rẹ, tíí ṣe ọmọ ìyá rẹ, tabi ọmọ rẹ, lọkunrin tabi lobinrin, tabi aya rẹ, tí ó dàbí ẹyin ojú rẹ, tabi ọ̀rẹ́ rẹ tí o fẹ́ràn ju ẹ̀mí ara rẹ lọ;


Nígbà kan rí kò wúlò fún ọ. Ṣugbọn nisinsinyii ó wúlò fún ọ ati fún mi.


Ǹ bá dá a dúró, kó máa wà lọ́dọ̀ mi, kí ó lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi dípò rẹ lákòókò tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìyìn rere.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan