Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Filemoni 1:10 - Yoruba Bible

10 mò ń bẹ̀ ọ́ nítorí ti ọmọ mi, Onisimu, ọmọ tí mo bí ninu ẹ̀wọ̀n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Emi bẹ̀ ọ fun ọmọ mi, ti mo bí ninu ìde mi, Onesimu:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Filemoni 1:10
14 Iomraidhean Croise  

Ó pàṣẹ fún Joabu, ati Abiṣai, ati Itai, ó ní, “Nítorí tèmi, ẹ má pa Absalomu lára.” Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì gbọ́ nígbà tí Dafidi ń pa àṣẹ yìí fún àwọn ọ̀gágun rẹ̀.


Ẹnìkan ninu wọn bá dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, ọmọ mi tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di odi ni mo mú wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.


Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ̀yin ará, mo fỌlọrun aláàánú bẹ̀ yín pé kí ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ bí ẹbọ mímọ́ tí ó yẹ láti fi sin Ọlọrun. Èyí ni iṣẹ́ ìsìn tí ó yẹ yín.


Kì í ṣe pé mo fẹ́ dójú tì yín ni mo fi ń kọ nǹkan wọnyi si yín, mò ń kìlọ̀ fun yín gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ mi ni.


Nítorí pé, ẹ̀ báà ní ẹgbẹrun àwọn olùtọ́ ninu Kristi, ẹ kò ní ju ẹyọ baba kan lọ. Nítorí ninu Kristi Jesu, èmi ni mo bi yín nípa ọ̀rọ̀ ìyìn rere.


Ẹ̀yin ọmọ mi, ara ń ni mí nítorí yín, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́, títí ẹ óo fi di àwòrán Kristi.


Mo tún rán Onisimu, ọ̀kan ninu yín, tí òun náà jẹ́ àyànfẹ́ ati arakunrin tí ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Gbogbo bí nǹkan bá ti rí níhìn-ín ni wọn óo ròyìn fun yín.


Sí Timoti ọmọ mi tòótọ́ ninu igbagbọ. Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Oluwa wa, kí ó máa wà pẹlu rẹ.


Mò ń kọ ìwé yìí sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ ninu ẹ̀sìn igbagbọ kan náà. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu Olùgbàlà wa, wà pẹlu rẹ̀.


Nígbà kan rí kò wúlò fún ọ. Ṣugbọn nisinsinyii ó wúlò fún ọ ati fún mi.


Ǹ bá dá a dúró, kó máa wà lọ́dọ̀ mi, kí ó lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi dípò rẹ lákòókò tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìyìn rere.


Ayọ̀ mi kì í lópin, nígbà tí mo bá gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń gbé ìgbé-ayé òtítọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan