Esteri 9:1 - Yoruba Bible1 Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari tíí ṣe oṣù kejila, nígbà tí wọ́n ń múra láti ṣe ohun tí òfin ọba wí, ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá rò pé ọwọ́ wọn yóo tẹ àwọn Juu, ṣugbọn, tí ó jẹ́ ọjọ́ tí àwọn Juu ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn; Faic an caibideilBibeli Mimọ1 Njẹ li oṣù kejila, eyini ni oṣù Adari, li ọjọ kẹtala rẹ̀, ti ofin ọba ati aṣẹ rẹ̀ sunmọle lati mu u ṣẹ, li ọjọ ti awọn ọta awọn Ju ti rò pe, awọn o bori wọn, (bi o tilẹ ti jẹ pe, ati yi i pada pe, ki awọn Ju ki o bori awọn ti o korira wọn;) Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari, tí ó yẹ kí a mú àṣẹ tí ọba pa wá sí ìmúṣẹ. Ní ọjọ́ yìí ni ọ̀tá àwọn Júù rò pé àwọn yóò borí i wọn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ti yìí padà, àwọn Júù sì na ọwọ́ agbára tó ga lórí àwọn tí ó kórìíra wọn. Faic an caibideil |