Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:9 - Yoruba Bible

9 Aláàánú ni ọ́ OLUWA Ọlọrun wa, ò sì máa dáríjì ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Sibẹ ti Oluwa Ọlọrun wa li ãnu ati idariji bi awa tilẹ ṣọ̀tẹ si i;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Olúwa Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ sí i;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:9
28 Iomraidhean Croise  

Dafidi dá Gadi lóhùn pé, “Ìdààmú ńlá ni ó dé bá mi yìí, ṣugbọn ó yá mi lára kí OLUWA jẹ wá níyà ju pé kí ó fi mí lé eniyan lọ́wọ́ lọ; nítorí pé, aláàánú ni OLUWA.”


Máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ ati adura àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, máa gbọ́ tiwa láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì máa dáríjì wá.


Ṣugbọn nítorí àánú rẹ ńlá, o kò jẹ́ kí wọ́n parun patapata, bẹ́ẹ̀ ni o kò pa wọ́n tì, nítorí pé Ọlọrun olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni ọ́.


Ṣugbọn ní ìkáwọ́ rẹ ni ìdáríjì wà, kí á lè máa bẹ̀rù rẹ.


Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA! Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà, ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà.


ati pé, tìrẹ, OLUWA ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Ò máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.


Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore; o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́.


Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA, o máa ń dárí jini; ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.


Kí eniyan burúkú fi ọ̀nà ibi rẹ̀ sílẹ̀, kí alaiṣododo kọ èrò burúkú rẹ̀ sílẹ̀, kí ó yipada sí OLUWA, kí OLUWA lè ṣàánú rẹ̀. Kí ó yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun wa, nítorí Ọlọrun yóo dáríjì í lọpọlọpọ.


N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́, n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀; nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa, ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli, tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀, ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀.


Àwọn eniyan mi ké pè mí wí pé, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ń jẹ́rìí lòdì sí wa, sibẹsibẹ, nítorí orúkọ rẹ, gbà wá. Ọpọlọpọ ìgbà ni a ti pada lẹ́yìn rẹ, a ti ṣẹ̀ ọ́.


Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli dìtẹ̀ sí mi ninu aṣálẹ̀, wọn kò pa òfin mi mọ́; wọ́n sì kọ ìlànà mi sílẹ̀, èyí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé yóo yè. Wọ́n ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́ patapata. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata ninu aṣálẹ̀.


“A ti ṣẹ̀, a ti ṣe burúkú; a ti ṣìṣe, a ti ṣọ̀tẹ̀, nítorí pé a ti kọ òfin ati àṣẹ rẹ sílẹ̀.


A kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn iranṣẹ rẹ, àní àwọn wolii, tí wọ́n wá jíṣẹ́ rẹ fún àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa, àwọn baba wa, ati fún gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà.


Olódodo ni ọ́, OLUWA, ṣugbọn lónìí yìí ojú ti gbogbo àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu, ati gbogbo Israẹli; ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn, níbi gbogbo tí o fọ́n wọn káàkiri sí nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí ọ.


OLUWA, ìtìjú yìí pọ̀ fún àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, ati àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.


Ó bá gbadura sí OLUWA, ó ní: “OLUWA, ṣebí ohun tí mo sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ nìyí, nígbà tí mo wà ní orílẹ̀-èdè mi? Nítorí náà ni mo ṣe sa gbogbo ipá mi láti sálọ sí Taṣiṣi; nítorí mo mọ̀ pé Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú ni ọ́, o ní sùúrù, o kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ò sì máa yí ibi tí o bá ti pinnu láti ṣe pada.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan