Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:8 - Yoruba Bible

8 OLUWA, ìtìjú yìí pọ̀ fún àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, ati àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Oluwa, tiwa ni itiju, ti awọn ọba wa, ati awọn olori wa, ati ti awọn baba wa, nitori ti awa ti ṣọ̀tẹ si ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Háà! Olúwa, àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:8
15 Iomraidhean Croise  

Nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun burúkú lójú òun, wọ́n sì ti mú òun bínú láti ìgbà tí àwọn baba ńlá wọn ti kúrò ní Ijipti, àní títí di òní olónìí.”


sibẹ, tí wọ́n bá ranti, tí wọ́n sì ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ tí wọ́n sọ pé, ‘àwọn ti ṣẹ̀, àwọn ti hu ìwà tí kò tọ́, àwọn sì ti ṣe burúkú,’


tẹ́tí sílẹ̀, bojú wò mí, kí o sì fetí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mò ń gbà tọ̀sán-tòru nítorí àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ, tí mo sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ ọ́. Wò ó, èmi ati ìdílé baba mi ti dẹ́ṣẹ̀.


Láti ìgbà àtijọ́, ẹnìkan kò gbọ́ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò tíì fi ojú rí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ń ṣe irú nǹkan wọnyi fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.


OLUWA, a mọ ìwà burúkú wa, ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.


nítorí gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará ilẹ̀ Juda ṣe láti mú mi bínú, àtàwọn ọba wọn, àtàwọn ìjòyè wọn, àtàwọn alufaa wọn, àtàwọn wolii wọn; àtàwọn ará Juda àtàwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.


Ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú? Kì í ṣe pé ara wọn ni wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń dójú ti ara wọn?


“Ohun tí ó tọ́ ni OLUWA ṣe, nítorí mo ti ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; ṣugbọn, ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan, ẹ kíyèsí ìjìyà mi; wọ́n ti kó àwọn ọdọmọbinrin ati ọdọmọkunrin mi lọ sí ìgbèkùn.


“A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun, ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá.


Adé ti ṣíbọ́ lórí wa! A gbé! Nítorí pé a ti dẹ́ṣẹ̀,


Kí o lè ranti, kí ìdààmú sì bá ọ, kí ìtìjú má jẹ́ kí o lè lanu sọ̀rọ̀ mọ́; nígbà tí mo bá dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Ó ti tàpá sí òfin mi ju àwọn orílẹ̀-èdè yòókù lọ, ó sì ti kọ ìlànà mi sílẹ̀ ju àwọn agbègbè tí ó yí i ká lọ. Wọ́n kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé ìlànà mi.


Aláàánú ni ọ́ OLUWA Ọlọrun wa, ò sì máa dáríjì ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan