Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:7 - Yoruba Bible

7 Olódodo ni ọ́, OLUWA, ṣugbọn lónìí yìí ojú ti gbogbo àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu, ati gbogbo Israẹli; ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn, níbi gbogbo tí o fọ́n wọn káàkiri sí nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Oluwa tirẹ li ododo, ṣugbọn tiwa ni itiju, gẹgẹ bi o ti ri loni; fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu, ati fun gbogbo Israeli, ti o sunmọ tosi, ati awọn ti o jina rére; ni gbogbo ilẹkilẹ, nibiti o gbe ti le wọn rè, nitori ẹ̀ṣẹ wọn ti nwọn ti ṣẹ̀ si ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 “Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:7
34 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa, nítorí ìwà burúkú wa ati ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí a dá, a rí i pé ìyà tí ìwọ Ọlọrun fi jẹ wá kéré sí ẹ̀ṣẹ̀ wa; o jẹ́ kí àwa tí a pọ̀ tó báyìí ṣẹ́kù sílẹ̀.


OLUWA Ọlọrun Israẹli, olódodo ni ọ́, nítorí díẹ̀ ninu wa ṣẹ́kù tí a sá àsálà títí di òní yìí. A wà níwájú rẹ báyìí pẹlu ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè dúró níwájú rẹ báyìí.”


Sibẹ, o jàre gbogbo ohun tí ó dé bá wa yìí, nítorí pé o ṣe olóòótọ́ sí wa, àwa ni a hùwà burúkú sí ọ.


Olódodo ni ọ́, OLUWA, ìdájọ́ rẹ sì tọ́.


Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru, ìtìjú sì ti bò mí.


Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ìpànìyàn, Ọlọrun, ìwọ Ọlọrun, Olùgbàlà mi, n óo sì máa fi orin kéde iṣẹ́ rere rẹ.


Ìwọ nìkan, àní, ìwọ nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ̀, tí mo ṣe ohun tí ó burú lójú rẹ, kí ẹjọ́ rẹ lè tọ́ nígbà tí o bá ń dájọ́, kí ọkàn rẹ lè mọ́ nígbà tí o bá ń ṣe ìdájọ́.


Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun.


Gbogbo àwọn oriṣa ni a óo dójú tì, ìdààmú yóo sì bá wọn. Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère yóo bọ́ sinu ìdààmú papọ̀.


Olódodo ni ọ́, OLUWA, nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́; sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ. Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú?


Juda yóo rí ìgbàlà ní ìgbà tirẹ̀, Israẹli yóo sì wà láìléwu. Orúkọ tí a óo máa pè é ni ‘OLUWA ni òdodo wa.’


Ó ní òun óo sọ wọ́n di ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba ayé. Wọn óo di ẹni ẹ̀gàn, ẹni ẹ̀sín, ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni tí a fi ń ṣẹ́ èpè ní gbogbo ibi tí òun óo tì wọ́n lọ.


Ẹ jẹ́ kí á dojúbolẹ̀ kí ìtìjú wa sì bò wá, nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wa; àtàwa, àtàwọn baba ńlá wa, a kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní.”


nítorí gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará ilẹ̀ Juda ṣe láti mú mi bínú, àtàwọn ọba wọn, àtàwọn ìjòyè wọn, àtàwọn alufaa wọn, àtàwọn wolii wọn; àtàwọn ará Juda àtàwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.


A óo gba Juda là, Jerusalẹmu yóo sì wà ní àìléwu, orúkọ tí a óo wá máa pè é ni ‘OLÚWA ni Òdodo wa.’ ”


Wọ́n yí i ká bí àwọn tí ó ń ṣọ́ oko, nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.


Ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú? Kì í ṣe pé ara wọn ni wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń dójú ti ara wọn?


Kí o lè ranti, kí ìdààmú sì bá ọ, kí ìtìjú má jẹ́ kí o lè lanu sọ̀rọ̀ mọ́; nígbà tí mo bá dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Nígbà náà ni ẹ óo ranti ìrìnkurìn ati ìwà burúkú yín, ara yín óo sì su yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ati ìwà ìríra yín.


Baba yóo máa pa ọmọ wọn jẹ láàrin yín; ọmọ yóo sì máa pa àwọn baba jẹ. N óo dájọ́ fun yín, n óo fọ́n gbogbo àwọn tí ó kù ninu yín káàkiri igun mẹrẹẹrin ayé.


Àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa àwọn tí wọ́n wà lókèèrè; idà yóo pa àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ìyàn yóo sì pa àwọn yòókù tí ogun ati àjàkálẹ̀-àrùn bá dá sí. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn patapata.


Nítorí náà, OLUWA ti mú kí ìyọnu dé bá wa, ó sì rọ̀jò rẹ̀ lé wa lórí; olódodo ni OLUWA Ọlọrun wa ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, sibẹ a kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀.


Gbọ́ tiwa, Ọlọrun mi, ṣíjú wò wá, bí àwa ati ìlú tí à ń pe orúkọ rẹ mọ́, ti wà ninu ìsọdahoro. Kì í ṣe nítorí òdodo wa ni a ṣe ń gbadura sí ọ, ṣugbọn nítorí pé aláàánú ni ọ́.


OLUWA, ìtìjú yìí pọ̀ fún àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, ati àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.


“N óo pàṣẹ pé kí wọ́n gbo gbogbo Israẹli jìgìjìgì láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ìgbà tí wọ́n bá fi ajọ̀ ku èlùbọ́, ṣugbọn kóró kan kò ní bọ́ sílẹ̀.


Èrè wo ni ẹ rí gbà lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, àfi ohun tí ń tì yín lójú nisinsinyii? Ikú ni irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí.


“Pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ OLUWA, àpáta ààbò yín, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tọ́. Olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì í ṣe àṣìṣe, ẹ̀tọ́ ní í máa ń ṣe nígbà gbogbo.


OLUWA yóo fọn yín káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí wọn yóo sì ṣẹ́kù ninu yín kò ní tó nǹkan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan