Daniẹli 9:6 - Yoruba Bible6 A kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn iranṣẹ rẹ, àní àwọn wolii, tí wọ́n wá jíṣẹ́ rẹ fún àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa, àwọn baba wa, ati fún gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. Faic an caibideilBibeli Mimọ6 Bẹ̃li awa kò si fi eti si awọn iranṣẹ rẹ, awọn woli, ti o sọ̀rọ li orukọ rẹ fun awọn ọba wa, awọn ọmọ-alade wa, ati awọn baba wa, ati fun gbogbo awọn enia ilẹ wa. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní6 Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà. Faic an caibideil |
“Nítorí náà, nisinsinyii Ọlọrun wa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, Ọlọrun tí ó bani lẹ́rù, Ọlọrun tí máa ń mú ìlérí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣẹ, má fi ojú kékeré wo gbogbo ìnira tí ó dé bá wa yìí, ati èyí tí ó dé bá àwọn ọba wa, ati àwọn olórí wa, àwọn alufaa wa, ati àwọn wolii wa, àwọn baba wa, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ, láti ìgbà àwọn ọba Asiria títí di ìsinsìnyìí.