Daniẹli 9:5 - Yoruba Bible5 “A ti ṣẹ̀, a ti ṣe burúkú; a ti ṣìṣe, a ti ṣọ̀tẹ̀, nítorí pé a ti kọ òfin ati àṣẹ rẹ sílẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ5 Awa ti ṣẹ̀, awa si ti nda ẹ̀ṣẹ, awa si ti ṣe buburu gidigidi, awa si ti ṣọ̀tẹ, ani nipa kikuro ninu ẹkọ́ rẹ, ati idajọ rẹ: Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní5 Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀. Faic an caibideil |
Nígbà náà, àwọn tí wọ́n sá àsálà ninu yín yóo ranti mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a bá kó wọn ní ìgbèkùn lọ, nígbà tí mo bá mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn tí ó ń mú wọn kọ̀ mí sílẹ̀ kúrò, tí mo bá sì fọ́ ojú tí wọ́n fi ń ṣe àgbèrè tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn. Ojú ara wọn yóo tì wọ́n nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati nítorí gbogbo ìwà ìríra wọn.