Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:3 - Yoruba Bible

3 Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ OLUWA Ọlọrun tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ mò ń gbadura tọkàntọkàn pẹlu ààwẹ̀; mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, mo sì jókòó sinu eérú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Emi si kọju mi si Oluwa Ọlọrun, lati ma ṣafẹri nipa adura ati ẹ̀bẹ, pẹlu àwẹ, ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ẽru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú àwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:3
30 Iomraidhean Croise  

Dafidi bá ń gbadura sí Ọlọrun pé kí ara ọmọ náà lè yá, ó ń gbààwẹ̀, ó sì ń sùn lórí ilẹ̀ lásán ní alaalẹ́.


Nígbà náà ni Ẹsira kúrò níwájú ilé Ọlọrun, ó lọ sí yàrá Jehohanani, ọmọ Eliaṣibu, ibẹ̀ ni ó sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà. Kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu nítorí pé ó ń banújẹ́ nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé.


Lẹ́yìn náà, mo pàṣẹ létí odò Ahafa pé kí á gbààwẹ̀, kí á lè rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọrun wa, kí á sì bèèrè ìtọ́sọ́nà fún ara wa ati àwọn ọmọ wa, ati gbogbo ohun ìní wa.


Ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́, mo dìde kúrò níbi tí mo ti ń gbààwẹ̀ pẹlu aṣọ ati agbádá mi tí ó ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́wọ́ sí OLUWA Ọlọrun mi, mo gbadura pé:


Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kan náà, àwọn ọmọ Israẹli péjọ pọ̀, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì ku eruku sí orí wọn.


“Lọ kó gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa jọ, kí ẹ gba ààwẹ̀ fún mi fún ọjọ́ mẹta, láìjẹ, láìmu, láàárọ̀ ati lálẹ́. Èmi ati àwọn iranṣẹ mi náà yóo máa gbààwẹ̀ níhìn-ín. Lẹ́yìn náà, n óo lọ rí ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin, bí n óo bá kú, kí n kú.”


nítorí náà, ojú ara mi tì mí, fún ohun tí mo ti sọ, mo sì ronupiwada ninu erùpẹ̀ ati eérú.”


Bẹ́ẹ̀ sì ni, ní tèmi, nígbà tí wọn ń ṣàìsàn, aṣọ ọ̀fọ̀ ni mo wọ̀; mo fi ààwẹ̀ jẹ ara mi níyà; mo gbadura pẹlu ìtẹríba patapata,


Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun fi ìpè sóde pé, kí ẹ máa sọkún, kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀, kí ẹ fá orí yín, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora.


“Ẹ ké pè mí, n óo sì da yín lóhùn; n óo sọ nǹkan ìjìnlẹ̀ ati ìyanu ńlá, tí ẹ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ fun yín.”


OLUWA Ọlọrun ní, “Ohun kan tí n óo tún mú kí àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ mi pé kí n ṣe fún àwọn ni pé kí n máa mú kí àwọn ọmọ wọn pọ̀ sí i bí ọ̀wọ́ aguntan.


Nígbà tí Daniẹli gbọ́ pé wọ́n ti fi ọwọ́ sí òfin náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó wọ yàrá òkè lọ, ó ṣí fèrèsé ilé rẹ̀ sílẹ̀, sí apá Jerusalẹmu. Ó kúnlẹ̀, ó ń gbadura, ó sì ń yin Ọlọrun, nígbà mẹta lojoojumọ.


èmi, Daniẹli bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀rọ̀ OLUWA, mò ń ronú lórí ohun tí Jeremaya, wolii sọ, pé Jerusalẹmu yóo dahoro fún aadọrin ọdún.


Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ èmi ati ti àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, mo kó ẹ̀bẹ̀ mi tọ OLUWA Ọlọrun mi lọ, nítorí òkè mímọ́ rẹ̀.


Mo gbadura sí OLUWA Ọlọrun mi, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi. Mo ní, “OLUWA Ọlọrun, tí ó tóbi, tí ó bani lẹ́rù, tíí máa ń pa majẹmu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́.


Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ sì sọkún, ẹ̀yin alufaa, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ẹ̀ ǹ ṣiṣẹ́ ní ibi pẹpẹ ìrúbọ. Ẹ̀yin òjíṣẹ́ Ọlọrun mi, ẹ wọlé, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora sùn, nítorí a ti dáwọ́ ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu dúró ní ilé Ọlọrun yín.


OLUWA ní, “Ẹ yipada sí mi tọkàntọkàn nisinsinyii, pẹlu ààwẹ̀, ẹkún ati ìkẹ́dùn,


Àwọn ará Ninefe gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbọ́, wọ́n bá kéde pé kí gbogbo eniyan gbààwẹ̀, àtọmọdé, àtàgbà, wọ́n sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.


Irú ẹ̀mí burúkú báyìí kò lè jáde àfi nípa adura ati ààwẹ̀.”]


Kọniliu dáhùn pé, “Ní ijẹrin, ní déédé àkókò yìí, mo ń gbadura ninu ilé mi ní agogo mẹta ọ̀sán. Ọkunrin kan bá yọ sí mi, ó wọ aṣọ dídán.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan