Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:16 - Yoruba Bible

16 OLUWA, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òdodo rẹ, dáwọ́ ibinu ati ìrúnú rẹ dúró lórí Jerusalẹmu, ìlú rẹ, òkè mímọ́ rẹ; nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára àwọn baba wa, ti sọ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan rẹ, di àmúpòwe láàrin àwọn tí ó yí wa ká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo ododo rẹ, lõtọ, jẹ ki ibinu ati irunu rẹ yi kuro lori Jerusalemu, ilu rẹ, òke mimọ́ rẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wa, ati ẹ̀ṣẹ awọn baba wa ni Jerusalemu, ati awọn enia rẹ fi di ẹ̀gan si gbogbo awọn ti o yi wa ka.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Olúwa, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jerusalẹmu ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa ti mú Jerusalẹmu àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:16
33 Iomraidhean Croise  

O rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí ọ, O sì bá a dá majẹmu láti fún àwọn ìran rẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati ti àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Amori, ti àwọn ará Perisi, ti àwọn ará Jebusi ati ti àwọn ará Girigaṣi, o sì ti mú ìlérí náà ṣẹ nítorí pé olódodo ni ọ́.


OLUWA, gbọ́ adura mi; fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi! Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ.


OLUWA, ìwọ ni mo sá di, má jẹ́ kí ojú tì mí lae; gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́.


Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae. Amin! Amin!


Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ; tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là!


A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa; àwọn tí ó yí wa ká ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n sì ń fi wá rẹ́rìn-ín.


Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa; dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró.


OLUWA àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ẹni tí o fi àmì òróró yàn ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń kẹ́gàn ìrìn ẹsẹ̀ rẹ̀.


O kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bọ wọ́n; nítorí Ọlọrun tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ẹ̀ṣẹ̀ baba bi ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ẹkẹrin lára àwọn tí wọ́n kórìíra mi.


Nítorí náà ni inú ṣe bí OLUWA sí àwọn eniyan rẹ̀, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì pa wọ́n, àwọn òkè sì mì tìtì. Òkú wọn dàbí pàǹtí láàrin ìgboro, sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì dá ọwọ́ ìjà dúró.


Ó ní òun óo sọ wọ́n di ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba ayé. Wọn óo di ẹni ẹ̀gàn, ẹni ẹ̀sín, ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni tí a fi ń ṣẹ́ èpè ní gbogbo ibi tí òun óo tì wọ́n lọ.


Ó ní, ‘N óo fi ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn bá wọn jà, òun óo sì sọ wọ́n di àríbẹ̀rù fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Wọn yóo di ẹni ègún, àríbẹ̀rù, àrípòṣé ati ẹni ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé wọn lọ.


Láti ọjọ́ tí wọn ti tẹ ìlú yìí dó títí di òní, ni àwọn ará ilẹ̀ yìí tí ń mú mi bínú, tí wọn sì ń mú kí inú mi ó máa ru, kí n lè pa wọ́n rẹ́ kúrò níwájú mi,


nítorí gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará ilẹ̀ Juda ṣe láti mú mi bínú, àtàwọn ọba wọn, àtàwọn ìjòyè wọn, àtàwọn alufaa wọn, àtàwọn wolii wọn; àtàwọn ará Juda àtàwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.


A ti dá ọ lẹ́bi nítorí àwọn eniyan tí o pa, o sì ti di aláìmọ́ nítorí àwọn ère tí o gbẹ́. O ti mú kí ọjọ́ ìjìyà rẹ súnmọ́ tòsí, ọdún tí a dá fún ọ sì pé tán. Nítorí náà, mo ti sọ ọ́ di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn eniyan, ati ẹni yẹ̀yẹ́ lójú gbogbo orílẹ̀-èdè.


N óo sọ yín di ahoro ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yi yín ká ati lójú gbogbo àwọn tí wọn ń rékọjá lọ.


Yóo kọ́ ààfin ńlá fún ara rẹ̀ ní ààrin òkun ati ní òkè mímọ́ ológo; sibẹ yóo ṣègbé, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn án lọ́wọ́.”


Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ èmi ati ti àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, mo kó ẹ̀bẹ̀ mi tọ OLUWA Ọlọrun mi lọ, nítorí òkè mímọ́ rẹ̀.


“Israẹli, o óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA, Ọlọrun rẹ, èmi ni mò ń gbé Sioni, òkè mímọ́ mi. Jerusalẹmu yóo di ìlú mímọ́, àwọn àjèjì kò sì ní ṣẹgun mọ́.


Ó ní, òun óo pada sí Sioni, òun óo máa gbé Jerusalẹmu, a óo máa pe Jerusalẹmu ní ìlú olóòótọ́, òkè OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati òkè mímọ́.


Nítorí ó tọ́ lójú Ọlọrun láti fi ìpọ́njú san ẹ̀san fún àwọn tí wọn ń pọn yín lójú,


Ṣugbọn bí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa: olóòótọ́ ati olódodo ni òun, yóo wẹ àìṣedéédé gbogbo nù kúrò lára wa.


OLUWA ni ó lè sọni di aláìní, òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀. Òun ni ó ń gbéni ga, òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan