Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:12 - Yoruba Bible

12 Ohun tí o sọ pé o óo ṣe sí àwa ati àwọn ọba wa náà ni o ṣe sí wa, tí àjálù ńlá fi dé bá wa. Irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí kò ṣẹlẹ̀ sí ìlú kan rí, ninu gbogbo àwọn ìlú ayé yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 On si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, eyi ti o sọ si wa, ati si awọn onidajọ wa ti o nṣe idajọ fun wa, nipa eyi ti o fi mu ibi nla bá wa: iru eyi ti a kò ti iṣe si gbogbo abẹ ọrun, gẹgẹ bi a ti ṣe sori Jerusalemu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:12
31 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà, OLUWA, fún èmi iranṣẹ rẹ ní ọgbọ́n láti darí àwọn eniyan rẹ, kí n lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi, nítorí pé, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ni lè ṣe àkóso àwọn eniyan rẹ tí wọ́n pọ̀ báyìí?”


‘OLUWA ní, “Wò ó n óo jẹ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan inú rẹ̀ níyà bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí ọba Juda kà.


Ó pa ọgbọ́n mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu, ó sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.


Ẹ yìn ín, ẹ̀yin ọba ayé ati gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ìjòyè ati gbogbo onídàájọ́ ayé;


Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin onídàájọ́ ayé, ẹ gba ìkìlọ̀.


Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso, gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé.


Nítorí náà mo sọ àwọn olórí ibi mímọ́ mi di aláìmọ́, mo fi Jakọbu sílẹ̀ fún ìparun; mo sì sọ Israẹli di ẹni ẹ̀sín.”


Èmi tí mo jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ iranṣẹ mi, tí mo sì mú ìmọ̀ àwọn ikọ̀ mi ṣẹ, èmi tí mo wí fún Jerusalẹmu pé, ‘Àwọn eniyan yóo máa gbé inú rẹ,’ tí mo sì wí fún àwọn ìlú Juda pé, ‘A óo tún odi yín mọ, n óo sì tún yín kọ́.’


Ọjọ́ ńlá lọjọ́ náà yóo jẹ́, kò sí ọjọ́ tí yóo dàbí rẹ̀, àkókò ìpọ́njú ni yóo jẹ́ fún ilé Jakọbu; ṣugbọn wọn yóo bọ́ ninu rẹ̀.”


Wọ́n dé ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á; ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, wọn kò sì pa òfin rẹ mọ́. Wọn kò ṣe ọ̀kan kan ninu gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn láti máa ṣe; nítorí náà ni o ṣe mú kí gbogbo ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn bá wọn!


kí ó lọ sọ fún Ebedimeleki ará Etiopia pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Wò ó, n óo mú ìpinnu ibi tí mo ṣe lórí ìlú yìí ṣẹ, lójú rẹ ni yóo sì ṣẹ.


Ìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀ si yín ni pé ẹ sun turari, ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ kò pa òfin, ati ìlànà rẹ̀ mọ́.”


Ó ní, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí kò kàn yín ni, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kọjá lọ? Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, kí ẹ ṣe akiyesi rẹ̀, bóyá ìbànújẹ́ kan wà tí ó dàbí èyí tí ó dé bá mi yìí; tí OLUWA mú kí ó dé bá mi, ní ọjọ́ ibinu gbígbóná rẹ̀.


Kí ni mo lè sọ nípa rẹ, kí sì ni ǹ bá fi ọ́ wé, Jerusalẹmu? Kí ni mo lè fi wé ọ, kí n lè tù ọ́ ninu, ìwọ Sioni? Nítorí bí omi òkun ni ìparun rẹ gbòòrò; ta ló lè mú ọ pada bọ̀ sípò?


OLUWA ti ṣe bí ó ti pinnu, ó ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, bí ó ti sọ ní ìgbà àtijọ́. Ó ti wó ọ lulẹ̀ láìṣàánú rẹ; ó ti jẹ́ kí ọ̀tá yọ̀ ọ́, ó ti fún àwọn ọ̀tá rẹ ni agbára kún agbára.


Ìjìyà àwọn eniyan mi pọ̀ ju ti àwọn ará Sodomu lọ, Sodomu tí ó parun lójijì, láìjẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn án.


Wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́, wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA wí báyìí.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò rán wọn níṣẹ́ kankan; sibẹ wọ́n ń retí pé kí OLUWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.


Nítorí gbogbo ìwà ìríra yín, n óo ṣe ohun tí n kò ṣe rí si yín, tí n kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́ lae.


Angẹli tí ó wọ aṣọ funfun náà ní, “Ní àkókò náà Mikaeli, aláṣẹ ńlá, tí ń dáàbò bo àwọn eniyan rẹ, yóo dìde. Àkókò ìyọnu yóo dé, irú èyí tí kò tíì sí rí láti ọjọ́ tí aláyé ti dáyé; ṣugbọn a óo gba gbogbo àwọn eniyan rẹ, tí a bá kọ orúkọ wọn sinu ìwé náà là.


Yóo jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Àwọn ọmọ ogun yóo bo gbogbo òkè ńlá, bí ìgbà tí òkùnkùn bá ń ṣú bọ̀. Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kò sì tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ títí lae.


“Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ láàrin gbogbo aráyé, nítorí náà, n óo jẹ yín níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.


Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi ati ìlànà mi tí àwọn wolii, iranṣẹ mi, sọ kò ṣẹ sí àwọn baba ńlá yín lára?” Àwọn eniyan náà bá ronupiwada, wọ́n ní, “OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ṣe wá bí ó ti pinnu láti ṣe, nítorí ìwà burúkú ati iṣẹ́ ibi wa.”


Mo rí ìran kan lóru. Ninu ìran náà, mo rí ọkunrin kan lórí ẹṣin pupa, láàrin àwọn igi kan tí wọ́n ń pè ní mitili, láàrin àfonífojì kan. Àwọn ẹṣin pupa, ati ẹṣin rẹ́súrẹ́sú ati ẹṣin funfun dúró lẹ́yìn rẹ̀.


Wọ́n ṣe agídí, wọ́n kọ̀ wọn kò gbọ́ òfin ati ọ̀rọ̀ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun fi agbára ẹ̀mí rẹ̀ rán sí wọn, láti ẹnu àwọn wolii. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun bínú sí wọn gidigidi.


Nítorí ìpọ́njú yóo pọ̀ ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyìí; irú rẹ̀ kò sì tún ní sí mọ́.


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, títí ọ̀run ati ayé yóo fi kọjá, kínńkínní, tabi ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ninu òfin, kò ní yẹ̀ títí gbogbo rẹ̀ yóo fi ṣẹ.


Nítorí ìpọ́njú yóo wà ní àkókò náà, irú èyí tí kò sí rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ohun gbogbo títí di àkókò yìí, kò sì ní sí irú rẹ̀ mọ́ lae.


Nítorí àkókò ẹ̀san ni àkókò náà, nígbà tí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ yóo ṣẹ.


Ohun tí mò ń sọ ni pé Kristi ti di iranṣẹ fún àwọn tí ó kọlà, láti mú òtítọ́ Ọlọrun ṣẹ, kí ó lè mú àwọn ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba-ńlá ṣẹ,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan