Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 9:10 - Yoruba Bible

10 A kò gbọ́ tìrẹ OLUWA Ọlọrun wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò pa òfin rẹ tí o fi rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ sí wa mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Bẹ̃li awa kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, lati ma rìn nipa ofin ti o gbé kalẹ niwaju wa lati ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Àwa kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, a kò sì pa àwọn òfin rẹ mọ́, èyí tí ó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 9:10
8 Iomraidhean Croise  

Ogun kó Samaria nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli kò pa òfin OLUWA Ọlọrun wọn mọ́, wọ́n si da majẹmu tí OLUWA bá wọn dá. Wọn kò pa àwọn òfin tí OLUWA fún Mose, iranṣẹ rẹ̀ mọ́, wọn kò sì gbọ́ràn.


Kí o dá wọn lóhùn pé, nítorí pé àwọn baba wọn ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé àwọn ọlọrun mìíràn, wọ́n ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń bọ wọ́n.


Wọ́n dé ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á; ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, wọn kò sì pa òfin rẹ mọ́. Wọn kò ṣe ọ̀kan kan ninu gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn láti máa ṣe; nítorí náà ni o ṣe mú kí gbogbo ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn bá wọn!


A kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn iranṣẹ rẹ, àní àwọn wolii, tí wọ́n wá jíṣẹ́ rẹ fún àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa, àwọn baba wa, ati fún gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà.


Ní ìgbà àtijọ́, oríṣìíríṣìí ọ̀nà ni Ọlọrun fi ń bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan