Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:8 - Yoruba Bible

8 Òbúkọ náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi sí i, ṣugbọn nígbà tí agbára rẹ̀ dé góńgó, ìwo ńlá iwájú rẹ̀ bá kán. Ìwo ńlá mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀. Wọ́n kọjú sí ọ̀nà mẹrẹẹrin tí afẹ́fẹ́ ti ń fẹ́ wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Nigbana ni obukọ na nṣe ohun nla pupọpupọ, nigbati o si di alagbara tan, iwo nla na ṣẹ́; ati nipò rẹ̀ iwo mẹrin miran ti iṣe afiyesi si yọ jade si ọ̀na afẹfẹ mẹrẹrin ọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:8
19 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn nígbà tí Usaya di alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ tì í ṣubú. Ó ṣe aiṣootọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó wọ inú tẹmpili OLUWA, ó lọ sun turari lórí pẹpẹ turari.


Modekai di eniyan pataki ní ààfin; òkìkí rẹ̀ kàn dé gbogbo agbègbè, agbára rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i.


n óo mú kí ẹ̀fúùfù mẹrin láti igun mẹrẹẹrin ojú ọ̀run kọlu Elamu; n óo sì fọ́n wọn ká sinu ẹ̀fúùfù náà, kò sì ní sí orílẹ̀-èdè kan tí àwọn ará Elamu kò ní fọ́n ká dé.


Ilé wọn kún fún ìwà ọ̀dàlẹ̀, bíi kùùkú tí ó kún fún ẹyẹ. Nítorí èyí, wọ́n di eniyan ńlá, wọ́n di olówó,


kí o sì dàgbà bí irúgbìn oko. Ni o bá dàgbà, o ga, o sì di wundia, ọyàn rẹ yọ, irun rẹ sì hù, sibẹ o wà ní ìhòòhò.


Ṣé o óo lè sọ pé oriṣa kan ni ọ́ lójú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ́? Nígbà tí wọ́n bá ń ṣá ọ lọ́gbẹ́, ṣé eniyan ni o óo wá pe ara rẹ àbí oriṣa.


Lẹ́yìn tí ó bá jọba, ìjọba rẹ̀ yóo pín sí ọ̀nà mẹrin. Àwọn ọba tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀ kò ní jẹ́ láti inú ìran rẹ̀, kò sì ní sí èyí tí yóo ní agbára tó o ninu wọn; nítorí a óo gba ìjọba rẹ̀, a óo sì fún àwọn ẹlòmíràn.


Kí ó tó wí bẹ́ẹ̀ tán, ẹnìkan fọhùn láti ọ̀run, ó ní, “Nebukadinesari ọba, gbọ́ ohun tí a ti pinnu nípa rẹ: a ti gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ rẹ,


Ṣugbọn nígbà tí ó gbé ara rẹ̀ ga, tí ó sì ṣe oríkunkun, a mú un kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, a sì mú ògo rẹ̀ kúrò.


Ó ní, “Bí mo ti sùn ní alẹ́, mo rí i lójúran pé afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ láti igun mẹrẹẹrin ayé ń rú omi òkun ńlá sókè.


“Bí mo ti ń wò mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó dàbí ẹkùn, òun náà ní ìyẹ́ mẹrin lẹ́yìn. Ó ní orí mẹrin. A sì fún un ní agbára láti jọba.


Ìtumọ̀ ìwo tí ó ṣẹ́, tí mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀, ni pé lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni ìjọba rẹ̀ yóo pín sí mẹrin, ṣugbọn kò ní jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.


Bí mo tí ń ronú nípa rẹ̀, mo rí i tí òbúkọ kan ti ìhà ìwọ̀ oòrùn la gbogbo ayé kọjá wá láìfi ẹsẹ̀ kan ilẹ̀, ó sì ní ìwo ńlá kan láàrin ojú rẹ̀ mejeeji.


Mo rí i ó súnmọ́ àgbò náà, ó fi tìbínú-tìbínú kàn án, ìwo mejeeji àgbò náà sì ṣẹ́. Àgbò náà kò lágbára láti dúró níwájú rẹ̀. Ó tì í ṣubú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà lọ́wọ́ rẹ̀.


Yóo wá rán angẹli rẹ̀ pẹlu fèrè ńlá, wọn yóo kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé; àní láti ìkangun ọ̀run kan dé ìkangun keji.


Yóo wá rán àwọn angẹli láti lọ kó àwọn àyànfẹ́ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé, láti òpin ayé títí dé òpin ọ̀run.


Nítorí pé, nígbà tí mo bá kó wọn wọ ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, tí mo ti búra pé n óo fún àwọn baba wọn; nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí wọ́n yó tán, tí wọ́n sì sanra, wọn óo yipada sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọn óo sì máa bọ wọ́n. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu mi.


Lẹ́yìn èyí, mo rí àwọn angẹli mẹrin tí wọ́n dúró ní igun mẹrẹẹrin ayé, tí wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹrẹẹrin ayé mú kí afẹ́fẹ́ má baà fẹ́ lórí ilẹ̀ ayé ati lórí òkun ati lára gbogbo igi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan