Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:4 - Yoruba Bible

4 Mo rí i tí àgbò náà bẹ̀rẹ̀ sí kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, kò sí ẹranko tí ó lè dúró níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti wù ú, ó sì ń gbéraga.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Mo si ri àgbo na o nkàn siha iwọ-õrùn, ati si ariwa, ati si gusu; tobẹ ti gbogbo ẹranko kò fi le duro niwaju rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹniti o le gbani lọwọ rẹ̀: ṣugbọn o nṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀, o si nṣe ohun nlanla.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, sí àríwá, àti sí gúúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó le è dojúkọ ọ́, kò sí ẹnìkan tí ó le è yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:4
18 Iomraidhean Croise  

Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Sedekaya, ọmọ Kenaana fi irin ṣe ìwo, ó sì wí fún Ahabu pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ohun tí ìwọ óo fi bá àwọn ará Siria jà nìyí títí tí o óo fi ṣẹgun wọn patapata.”


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ pé n kò lẹ́bi, ati pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ.


Nípa agbára rẹ ni a fi bi àwọn ọ̀tá wa sẹ́yìn, orúkọ rẹ ni a fi tẹ àwọn tí ó gbógun tì wá mọ́lẹ̀.


“Nítorí náà, ẹ fi èyí lékàn, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọrun, kí n má baà fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì ní sí ẹni tí yóo gbà yín kalẹ̀.


Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun, kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀.


Nítorí pé ẹ̀ ń fi ẹ̀gbẹ́ ti àwọn tí wọn kò lágbára sọnù, ẹ sì ń kàn wọ́n níwo títí tí ẹ fi tú wọn ká.


Ọba Siria yóo ṣe wọ́n bí ó ti fẹ́ láìsí àtakò, yóo dúró ní Ilẹ̀ Dáradára náà, gbogbo rẹ̀ yóo sì wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.


“Ohun tí ó bá wu ọba náà ni yóo máa ṣe; yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo oriṣa lọ, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo máa sọ̀rọ̀ tó lòdì sí Ọlọrun àwọn ọlọrun, yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i títí ọjọ́ ibinu tí a dá fún un yóo fi pé; nítorí pé ohun tí Ọlọrun ti pinnu yóo ṣẹ.


Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀.


Ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an ni wọ́n pa Beṣasari, ọba àwọn ará Kalidea.


“Ẹranko keji dàbí àmọ̀tẹ́kùn, ó gbé ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan sókè. Ó gbé egungun ìhà mẹta há ẹnu, ó wa eyín mọ́ ọn. Mo sì gbọ́ tí ẹnìkan sọ fún un pé, ‘Dìde, kí o sì máa jẹ ẹran sí i.’


Mo rí i ó súnmọ́ àgbò náà, ó fi tìbínú-tìbínú kàn án, ìwo mejeeji àgbò náà sì ṣẹ́. Àgbò náà kò lágbára láti dúró níwájú rẹ̀. Ó tì í ṣubú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà lọ́wọ́ rẹ̀.


Àwọn ọmọ Israẹli yòókù yóo wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ati ọ̀pọ̀ eniyan, bíi kinniun láàrin àwọn ẹranko igbó, bíi ọ̀dọ́ kinniun láàrin agbo-aguntan, tí ó jẹ́ pé bí ọwọ́ rẹ̀ bá tẹ ẹran, yóo fà á ya, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.


Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù, Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára, tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu, ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan